You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
FIFA: Super Eagles bọ́ sí ipò kẹrin ní Afrika
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Ipo kẹtadinlaadọta ni orilẹede ẹgbẹ agbabọọlu Super eagles Naijiria ṣi wa, lori atẹ igbelewọn awọn orilẹede to n gba bọọlu lagbaye fun oṣu karun eleyii to jade lọjọbọ.
Amọ ni ilẹ Afirika, ipo kẹrin ni Super Eagles sun si bayii lati ipo kẹfa ti wọn wa tẹlẹ.
Awọn ikọ agbabọọlu orilẹede Argentina, Croastia ati Iceland ti Super Eagles yoo koju, ni idije ife ẹyẹ agbaye wa ni ipo karun-un, ikejidinlogun ati ikejilelogun ni ṣisẹ n tẹle, lori atẹ igbelewọn awọn orilẹede to n gba bọọlu lagbaye.
Orilẹede Germany lo ṣi n gbe ipo kinni, ti brazil si n tẹle e.