Soyinka: Mo mọ ibití màá dìbò mi sí

Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Sóyínká

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Sóyínká ní òun mọ ibití òun yóò di ìbò òun sí.

Ìlúmọ̀ọ́ká alámì ẹ̀yẹ òǹkọ̀wé nnì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Sóyínka, ti késí àwọn ọmọ Nàíjíríà láti máa fojú sọ́rí, kí wọn má sì jẹ́ káwọn èèyàn tó ba ilẹ̀ yìí jẹ́, máa gbé wọn mọ́ra, nítorí bí wọn se ń fi ara wọn hàn báyìí gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà.

Sóyínká gbé ìmọ̀ràn yìí kalẹ̀ lọ́jọ́ àìkú pẹ̀lú gbajúgbajà agbẹjọ́rò àti akétantan kí ọlọ́rọ̀ gbọ́ nnì, Fẹ́mi Fálànà, ní ibi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọn fi sọrí ọgọ́rin ọdún tí wọn bí ìlúmọ̀ọ́ká ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni àti àgbà amòfin nnì, olóògbé Gani Fáwẹ̀hìnmi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Aragbe laye'

Sóyínká ní òun ti ní èrò tòun nípa ẹgbẹ́ òsèlú APC tó ń sèjọba lọ́wọ́, tóun sì mọ ibití òun yóò di ìbò òun sí.

"Ẹ máse gbàgbé àwọn ìsẹ̀lẹ̀ àti ìwà ibi táwọn olósèlú kan ti hù látẹ̀yìn wàá, sùgbọ́n ń se ni kẹ́ẹ padà lọ rántí àkọsílẹ̀ àwọn ògbólógbòó olósèlú yìí àti ẹgbẹ́ tí wọn ń kó, nítorí ohun táa bá se lónìí, ọ̀rọ̀ ìtaàn ni yóò dà bó dọ̀la."

Àgbà Amọ̀fin Fẹ́mi Fálànà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Èèyàn kan fi ọdún mọ́kànlá àti ààbọ̀ sèjọba láì ní àseyọrí

Bàkan náà ni Fálànà sọ pé orílẹ̀èdè Nàíjíríà ń kojú ìsòro ìsèjọba tó lágbára, tó sì késí àwọn ọmọ orílẹ̀èdè yìí láti máa fojú sọ́rí bíi alákàn, kí wọn má baà gba àwọn èèyàn tó ti ba orílẹ̀èdè yìí jẹ́ tẹ́lẹ̀, láti máa padà yọjú bíi Olùgbàlà wa.

Èèyàn kan fi ọdún mọ́kànlá àti ààbọ̀ sèjọba láì ní àseyọrí

"Ẹnìkan wà tó ń gbé ibi tó súnmọ́ ibí yìí, tó ń fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà àwọn ọmọ Nàíjíríà. Ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ ló fi darí Nàíjíríà gẹ́gẹ́ bíi ológun, tó sì tún lo ọdún mẹ́jọ gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ alágbádá, tí àpapọ̀ iye ọdún tó fi tu ọkọ̀ Nàíjíríà jẹ́ ọdún mọ́kànlá àti ààbọ̀. Kódà, ó fẹ́ se sáà kẹta lórí oyè, a kò gbà fun ni. Ó tún ti wá ń lọ báyìí, tó sì ń polongo pé òun ní ojútùú sí ìsòro Nàíjíríà. Ó dùn mìí pé kò sí níbí. N kò bá bíí pé kó sọ ohun kan soso tó se fún Nàíjíríà."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sẹ́nẹ́tọ̀ Shehu Sanni naa ké sáwọn ọmọ Nàíjíríà láti máse fi ẹgbẹ́ òsèlú dìbò àmọ́ kí wọn dìbò wọn fún ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọn ní ìgbẹkẹ̀lé nínú rẹ̀.