Femi Falana: Laisi ọ̀pá àsẹ, ilé asòfin leè jíròrò

Femi Falana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbẹjọ́ro ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn Femi Falana lo ti sọ pe, kii se dandan kí ọ̀pá àsẹ ile ìgbìmọ̀ asòfin wà láàárín ilé kí awọn asòfin to leè jíròrò.

Ninu àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Àìkú ni ọ̀gbẹ́ni Falana ti fojú ọ̀rọ̀ naa léde.

Falana fi abala kẹrìnlẹ́láàádọ́ta òfin ilẹ̀ Naijiria kín ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn, o ni òfin sọ pe, ni ile ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ati kékéré, awọn ọmọ ilẹ́ ìgbìmọ̀ lẹ́tọ́ lati sèpàdé tí iye ọmọ ile ìgbìmọ̀ ti òfin fi lélẹ̀ ba ti wà ní ìkàlẹ̀.

Falana sọ̀rọ̀ yìí gẹ́gẹ́ bi èrò tirẹ̀ lori bí àwọn jàǹdùkú kan se ya wọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin lọ́sẹ̀ tó kọja, tí wọ́n sì jí ọ̀pá àsẹ ilé gbé.

Ọgbẹ̀ni Falana tẹnu mọ́ọ pe, ko si ibikíbi ninu ìwé òfin Naijiria, ti òfin ti sọ pe ìpàdé ile kò le tẹ̀síwájú láìsí ọ̀pá àsẹ.