Rochas Okorocha: Buhari yoo s'ọrọ lori ibo 2019 laipẹ

Rochas Okorocha

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Rochas Okorocha: Buhari yoo s'ọrọ lori ibo 2019 laipẹ

Gomina ipinlẹ Imo ati alaga igbimọ awọn gomina l'ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Rochas Okorocha ti sọ wi pe Aarẹ Muhammadu Buhari yoo sọ fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria laipẹ boya yoo tun gbe'gba idije ninu idibo ti ọdun 2019.

Okorocha sọrọ yi ni ọjọbọ lẹhin ti oun ati awọn gomina ẹgbẹ rẹ yoku ṣe ipade pẹlu Aarẹ Buhari nilu Abuja lalẹ ana.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ranpẹ pẹlu awọn oniroyin lẹhin ipade naa, Okorocha sọ pe awọn wa lati bẹ Aarẹ Buhari pe ki o jọwọ gbe'gba ibo lọdun to n bọ.

"A sọrọ lori ọpọlọpọ awọn ọrọ ti o niiṣe pẹlu eto orilẹede yi lapapọ, nipa ẹgbẹ o'selu APC ati eto idibo fun ọdun 2019."

Gomina ipinlẹ Imo naa salaye siwaju sii wi pe, "Ohun ti agbajọpọ awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC n fẹ ni ki Aarẹ Buhari o du ipo aarẹ lẹẹkan sii nitori iṣẹ takun takun rẹ ti o ti ṣe lati ọdun diẹ sẹyin. A ni igbagbọ pe bi o ba tẹsiwaju, orilẹede yii yoo dara sii. "

O tun sọ pe Aarẹ Buhari ti beere pe ki awọn gomina "fun oun ni akoko diẹ lati ronu sii, ati pe oun yoo ba awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria sọrọ laipẹ ti oun yoo ba dupo".

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC ti n ba Aarẹ Buhari sọrọ lati gbe'gba ibo

Awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC ti n ba Aarẹ Buhari sọrọ lati gbe'gba ibo. Wọn ṣe ipade pẹlu rẹ ni ọsẹ to kọja ni ilu rẹ ni Daura lori ọrọ yii bakanna.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: