Bola Tinubu: Ọbasanjo, IBB, ẹ lọ rọ ọ kun ni'le

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Adari agba fun ẹgbẹ oselu APC lorilẹede Naijiria, Asiwaju Bọla Tinubu ti parọwa si aarẹ tẹlẹri, Olusegun Obasanjo ati Ibrahim Babangida lati lọ rọ ọ kun sile bi awọn akẹgbẹ wọn to ti jẹ olori orilẹede ri .
Tinubu sọ eyi lọjọ iṣẹgun nigba to n ba awọn akọroyin ile iṣẹ ijọba apaapo sọrọ lẹyin ipade rẹ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari.
O ni o pọn dandan ki awọn adari tẹlẹri o darapọ mọ awọn to ti ṣiṣẹ fẹyinti, ki wọn si faaye silẹ lati jẹ ki orilẹede Naijiria o ni idagbasoke.
Ninu ọrọ rẹ, asiwaju Tinubu sọ wi pe ipo tuntun ti aarẹ fi ohun si naa ni lati laja laarin gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ APC.
O ni inu ohun dun pupọ si ipo asaaju naa ati wipe ohun yoo sa gbogbo ipa ohun lati mu ilọsiwaju ba ẹgbẹ oselu APC ati orilẹede lapaapọ.








