Nigeria Army Recruitment 2020: Wo bí o ṣe le fi orúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ ológun Nàìjíríà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileesẹ ológun Naijiria ti ṣi oju opo itakun agbaye rẹ fun eto igbani sisẹ fun ọdun 2020.

Eto naa wa awọn to fẹ ẹ fi orukọ silẹ fun: Direct Short Service Commission' ati fun 'Short Service Combatant commission' .

Olú ileesẹ ọmọ ogun to fi ikede naa sita lori ayelujara Twitter rẹ, sọ pe l'oju ẹsẹ ni iforukọ silẹ yoo bẹrẹ lori ayelujara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọn fi kun ikede naa pe gbogbo ọmọ bibi orilẹ-ede Naijiria ni eto igbani wọle fun SSC wa fun, to fi mọ awọn to n sisẹ ologun lọwọ.

Wo bi o ṣe le fi orukọ silẹ:

Igbesẹ fun ẹnikẹni to ba nífẹ̀ẹ́ lati fi orukọ silẹ ni lati lọ si oju opo ayelujara recruitment.army.mil.ng tabi ayelujara ti ileesẹ ologun Naijiria gan-an-gan, tẹ bọtinni to ni 'recruitment', ki o si yan SSC tabi DSSC ni oju ewe to ba ṣi.

Lati ibẹ, yan eto ti o ba koju oṣuwọn fun.

Fi orukọ silẹ fun iṣẹ ologun Naijiria nibi.

Ọ̀fẹ́ ni iforukọsilẹ:

Lẹyin naa ni ki o ti ọwọ bọ fọọmu to wa nibẹ. Lati sisẹ lori fọọmu naa, o nilo foto pelebe, awọn iwe ẹri ileewe ti o lọ, ẹri idanimọ gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ akọṣẹmọṣẹ kankan ti o ba ni, iwe ẹri lati ipinlẹ ti o ti wa, iwe ẹri ọjọ ori tabi iwe ibura ọjọ ori rẹ.

Dandan ni fun gbogbo ẹni to ba fi orukọ silẹ lati tẹ ìwé pelebe to ni fọto jade, lẹyin ti wọn ba kọ akọsilẹ sori fọọmu naa tan.

Idi ni pe, Akọwe ile ẹjọ yoowu ni yoo buwọlu oju ìwé akọkọ, ti Alaga tabi Akọwe ijọba ibilẹ rẹ yoo si buwọlu oju iwe keji. Sugbọn sa, Ọga Agba nileesẹ ologun to wa ni ipo Colonel tabi eyi to jọ ọ, to si jẹ ọmọ ipinlẹ rẹ naa le ba ọ buwọlu dipo Alaga ijọba ibilẹ.

Gbogbo eto iforukọ silẹ ko gbọdọ kọja ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹsàn-án, ọdun 2020.

Awọn amuyẹ to gbọdọ ni:

  • Ẹni to ba fẹ ẹ fi orukọ silẹ gbọdọ jẹ ọmọ bibi orilẹ-ede Naijiria.
  • O gbọdọ ga ju 1.68m lọ (ọkunrin), tabi 1.65m fun obinrin.
  • Ilera rẹ gbọdọ duro daadaa
  • Ko gbọdọ si akọsilẹ pe ile ẹjọ ti da ọ l'ẹbi ri fun iwa ọdaran
  • Ọjọ ori ẹni to fẹ ẹ fi orukọ silẹ gbọdọ ti pe ọdun mẹtalelogun si mẹtadinlọgbọn ti yoo ba fi di oṣu Kinni, ọdun 2021
  • O gbọdọ ni iwe ẹri ọjọ ori ti ajọ to n mojuto bi eeyan ṣe pọ si ni Naijiria, National Population Commission fi ọwọ si.
  • O si tun le jẹ ti ileewosan, ijọba ibilẹ, tabi ibura ( age declaration)
  • Ẹni to ba fẹ ẹ fi orukọ silẹ gbọdọ ni iwe ẹri ti ko kere ju ti imọ ijinlẹ akọkọ (first degree), pẹlu maaki ti ko kere ju 'Second Class Lower Division' lọ
  • O le lo iwe ẹri HND naa, pẹlu maaki ti ko kere ju 'Lower Credit' lọ
  • Awọn iwe ẹri yii gbọdọ jẹ lori ẹ̀kọ́ nipa 'arts,' science' , tabi' humanities' , lati ileewe ti ijọba fi ontẹ lu
  • Ko tan sibẹ o, àwọn olukopa gbọdọ fi lẹta ijẹri lati ileewe giga ti wọn lọ, silẹ
  • Olukopa kankan ko gbọdọ ni tatuu tabi kọ ohunkohun si ara
  • Olukopa gbọdọ ti pari eto agunbanirọ (NYSC), ni iwe ẹri NYSC, tabi iwe ti ajọ naa ma n fun awọn ti ko ba lọ fun eto naa
  • Awọn olukopa ko gbọdọ jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun kankan.

'Ẹ fun mi ni oku abi aaye Shekau'

Olori ọmọogun oriilẹ l'orilẹede Naijiria, Tukur Buratai ti rawọ ẹbẹ s'awọn ọmọ ogun orilẹede yi lati gbe Abubakar Shekau, tii se olori igun kan ninu ikọ adunkoko mọni Boko Haram, wa fun oun ni aaye abi ni oku.

Ọgagun Buratai parọwa yi nibudo Camp Zero, tii se ibujoko ibuba tẹlẹ f'awọn adunkoko mọni naa ninu igbo Sambisa lasiko abẹwo to se sawọn ọmọogun naa.

Awọn ibudo miran ti Buratai tun s'abẹwo si ninu igbo Sambisa ni Bita ati Tukumbere, ti gbogbo awọn adunkoko mọni ti fẹsẹ fẹẹ nibẹ

"Ẹ jẹ ki n ki yin ku oriire, amọ o yẹ ka kọja lọ s'ibiti ọkunrin ọdaran yi, Shekau wa, ka si mu laaye. Mo fẹ kẹ bami muu."

"Bakannaa ni aarẹ orilẹede yi ati oludari agba fun ileesẹ ologun orilẹede yi n ki yin ku oriire lori bi ẹ se gba igbo Sambisa. Ni tiwa, a ti de opin akanse ikọlu yi, eyiti ise lile awọn adunkoko mọni kuro ninu igbo Sambisa."

Ọgagun Buratai ti wa seleri pe ileesẹ ologun yoo mu ayipada rere ba igbo Sambisa, ti wọn yoo si sọ igbẹ rẹ digboro. Ati wipe, wọn yoo se agbekalẹ oniruuru ibudo awọn ologun sinu igbo ẹrujẹjẹ naa.