Mpape Crushed Rock: Àrímáleèlọ, àwòpadàsẹ́yìn ni ẹwà ibùdó yìí

Wọn ni bi Oluwa ba n se rere, a lo n se ibi ni nitori awamaridi ni isẹ Olodumare.

Ibudo to wa di ayawaawo nilu Abuja bayii lo jẹ ibudo ti wọn ti n wa kusa okuta tẹlẹ.

Ibudo naa, ti ọpọ eeyan mọ si Kuari lo ti wa di ibi ti ọwọ eeyan n peju wa wo lẹyin ti awọn eeyan kan ju aworan naa sori ayelujara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ibudo naa, ti wọn pe ni Crushed Rock, ti itumọ rẹ n jẹ apata ti wọn run wẹlẹwẹlẹ lo wa ni agbegbe Mpape nitori ilu Abuja.

Awọn apata to ku fun okuta girafu ni wọn ti gbẹ wọlẹ amọ awọn eyi ti wọn ko tii gbẹ, lo ga fiofio wọ oju ọrun eyi to mu ko rẹwa pupọ.

Awọn ọmọ naijiria ti wọn fẹran lati maa gbafẹ́ kiri nitori ooru to mu lẹkun ariwa Naijiria ati ilọwọwọ lẹkun guusu.

Ọpọ awọn olorin, onijo ati alafẹ si lo ti n ya lọ sibudo naa lati da ara wọn lara ya.

Koda, arun Coronavirus to n ja kiri yii tun mu ki awọn ọdọ nifẹ lati lọ se abẹwo si ibi ti ẹwa ayika pin si naa.

Bẹẹ ba gbagbe, ofin konile o gbele naa lo ti kọkọ da awọn awọn eeyan lọwọ kọ lati lọ sibi to jinna, yatọ si ayika wọn.

Itumọ Mpape ni Apata ni ede Gwari, ibudo yii si ni wọn ti ri ọpọ okuta girafu ti wọn lo fi sọ ilu Abuja di ilu nla ni saa ọdun 1980.

O le ni ọdun mẹwa ti wọn fi n wa okuta ni agbegbe yii, ti ẹ́nu si wa n ya awọ̀n olugbe adugbo naa lori bi ọpọ ero si n ya ba wọn ni alejo.

Oniruuru ibudo igbafẹ to jẹ oju ni gbese lo wa yika orilẹede Naijiria amọ̀ ni ibudo ẹwa atọwọda naa, ẹka mẹta ọtọọtọ lo mu ko wu oju ri.

Akọkọ, wọn le fi ẹsẹ rin lori koriko lati gun oke arẹwa ọhun.

Bi oke si se n ga si, naa lo n lewu si lati sọkalẹ.

sugbọn ikilọ wa fawọn akikaju onwẹ to ba fẹ re sinu omi, awọn olugbe ibẹ ni o kun fun awọn ohun eelo iwakusa lorisirisi ti omi ti bo mọl.

Gẹgẹ bi Abraham Adepelumi, tii se onimọ̀ nipa ayika ni fasiti Obafemi Awolowo ti wi, wọn da adagun omi naa silẹ nitori ọna atijẹ.