Jumoke Odetola: Ọ́pọ̀ òṣèré koro ojú sí àṣehàn lásán lẹ́yìn ikú akẹẹgbẹ́ wọn, Williams Aanuoluwapo, Kumbalee

Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá kọjú ìjà síra wọn lórí ìdárò akẹẹgbẹ́ wọn tó kú

Awaye ku ko si, Ọba oke mase jẹ ka fi ọjọ ọlọjọ lọ ni.

Ọfọ nla ti sẹ ni agbo ere tiata ni ọjọ Aje, eyi to dori awọn irawọ osere kodo.

Iku tun to wọ agbo awọn oṣere tiata nilẹ yii naa, nigba ti yoo si fi jade, ọkan lara awọn aṣaraloge (Makeup Artist) lẹka ere tiata Yoruba, lo mu lọ.

Orukọ oloogbe naa ni Williams Anuoluwapọ, ti ọpọ mọ si Kumbalee.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin ti a gbọ sọ pe, ijamba ọkada kan to waye lọjọ Aiku lo sọ Kumbalee di ero ọrun.

Idaji kutu hai owurọ ọjọ Isẹgun ni irawọ osere kan, Jumoke Odetola lo tufọ oloogbe naa, ti ọpọ akẹẹgbẹ rẹ lagbo tiata si n tara poro lori iku aitọjọ naa.

Sugbọn awọn ọrọ ti awọn osere kan n sọ lori iku ọkunrin naa ati awọn eeyan to n sọfọ rẹ, n kọ ni lominu.

Eyi si lo mu kawọn osere tiata kan fajuro lori ohun tawọn akẹẹgbẹ wọn n kọ nipa iku ọkunrin naa, ti wọn si n gbena woju ara wọn.

Sugbọn ọrọ aro ti ọpọ wọn n kọ soju opo Instagram wọn lo safihan pe, wọn n paroko ọrọ ransẹ saarin ara wọn, to si ni itumọ to jinlẹ.

Ọrọ naa lo ni o dara lootọ ki awọn eeyan daro iku ẹni to ba di oloogbe amọ irufẹ idaro bayii gbọdọ ni odiwọn.

O ni ojiji aye lasan ni gbogbo wa n le kiri, ta si n jẹ gaba lori awọn eeyan miran lai mọ ohun ti yoo sẹlẹ ni isẹju meji si asiko yii.

"Gbogbo wa la n waasu nipa bi aye se jẹ asan, sibẹ awa kan ni orisun isoro ara wa, o n waasu ifẹ, ti ikorira si gba ọkan rẹ kan.

Ọpọ wa ni ko bikita nipa ọjọ ọla wa, oni nikan la n naani rẹ, eyi to sọ wa di ẹni ibi pẹlu ọpọ ibanujẹ, ta si joko si kọrọ ile wa lati maa se idajọ lori awọn asise ẹlomiran."

Ọrọ naa wa kadi nilẹ pe ọjọ kan yoo jọkan, laarin isẹju kan, ti gbogbo rẹ yoo tan, ti yoo si ku wa ati iwa wa ninu saare.

Ọpọ osere tiata lo pin akanse ọrọ yii loju opo Instagram wọn, ti wọn si fi akọle tiwọn sibẹ.

Arike Abiodun Best lo sọrọ pe:

"Ti mo ba ku loni, ti o ko si gbe aworan mi soju opo ayelujara rẹ ri tẹlẹ , paapa lajọ ibi mi, ma wulẹ sopo gbe aworan mi lẹyin ti mo ba ku tan nitori maa ri ninu saare mi, ti maa si di igbaju olooyi lu ọ lati inu saare mi."

Bakan naa ni Mustipha Sholagbade gbe ọrọ yii soju opo rẹ, to fi mọ awọn osere tiata miran.

Nigba to ya ni agba osere tiata kan, Yomi Fabiyi bẹrẹ si da awọn akẹẹgbẹ rẹ lẹkun lori ọrọ naa, ati bi wọn se n daro oloogbe lọna to mu ikunsinu lọwọ.

Fabiyi ni ọrọ iku lagbara pupọ, to si wuwo, pẹlu afikun pe tawọn akẹẹgbẹ oun ko ba lee mọ ẹni to nifẹ wọn denu loju aye, bawo ni wọn se fẹ sedamọ rẹ ninu saare.

O ni atako ko wulo rara lasiko yii, yoo si dara ki wọn lo ohun wọn fun nnkan miran to ba wulo fun iran ọmọniyan, eto oselu ibaradọgba ati idajọ ododo.

O fikun pe ko dara ki wọn maa pa awọn eeyan kan lẹnu mọ tabi sọ irufẹ ẹni ti yoo daro wọn leti iboji ki araye ba le mọ pe wọn mọ ọrọ sọ.

"Eyi n ba ni ninu jẹ, yoo si dara kẹ jẹ kawọn eeyan se idaro oloogbe to ba se wu wọn, ki wọn si fi Ọlọrun silk lati se idamọ awọn eeyan eke ati awọn olootọ ẹda."

Theladyjokelet loju opo tiẹ naa wa n fi ika hanu lori ihuwasi awọn osere tiata Yoruba naa, eyi to ni o n ba oun ninujẹ.Ọfọ sẹ lagbo osere tiata, awọn osere kan n tahun sira wọn tori

Koda, ilumọọka osere tiata lobinrin, Jumọkẹ Odetola gan bara jẹ pupọ lori iku asaraloge naa, ẹni to salaye pe o papoda lẹyin wakati diẹ ti wọn sọrọ lori aago.