You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Libya shipwreck: Aṣàtìpó lọ sí Yuropu 45 kú sínú òkun ní Libya, 37 m'órí bọ́
O kere tan aṣatipo marundinlaadọta lo dero ọrun, lẹyin ti engini ọkọ oju omi to n gbe wọn lọ si ilẹ Yuropu lati Libya gbina ti wọn si ja sinu okun.
Igbimọ ajọ iṣọkan agbaye to n ri si ọrọ awọn aṣatipo, UNHCR lo fidi ọrọ naa mulẹ.
Awọn mẹtadinlọgbọn tawọn apẹja doola ẹmi wọn ṣalaye pe, awọn ọmọde marun un wa lara awọn to bomi lọ naa.
- Ikú Williams Aanuoluwa lágbo òṣèré hú ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ síta
- Àlàyé rèé lórí bo ṣe le è dá Emèrè mọ̀ tàbí dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ wọn
- Àṣírí ńlá tó ń bẹ láàrín Alaafin àtàwọn onílù rẹ̀ rèé
- Àwọn ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
- Wo ibùdó arẹwà tí ọ̀pọ̀ èrò ń ya lọ ní Abuja
Ajọ iṣọkan agbaye ati ajọ to n ri si ṣiṣikiri awọn eeyan to n rinrin ajo lori omi okun ti sọ pe awọn to n doola ẹmi awọn arinrin-ajo lori omi gbodọ pọ si.
Wọn lai jẹ bẹẹ, awọn to maa ṣegbe si inu omi okunyoo tubọ maa pọ si.
Akọsilẹ fihan pe awọn aṣikiri to le ni ọdunrun un lo ti ku sinu okun Mediterranean lọna irin ajo wọn lati Libya si ilẹ Yuropu.
Lati ọdun 2011 ti olori orilẹede Libya tẹlẹ, Muammar Gaddafi ti ku ni awọn aṣatipo ti n gba ibẹ lọ sọda si Yuropu.
Ẹwẹ, awọn ti ori iṣẹlẹ ko yọ ninu iṣẹlẹ Ọjọru ti wa lahamọ bayii ni Libya lẹyin ti wọn doola ẹmi wọn tan.
Awọn aṣatipo naa ni a gbọ pe wọn wa lati orilẹede Senegal, Mali, Chad ati Ghana.