You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kano Woman who killed son: Obìnrin kan dèrò ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó fi ọ̀bẹ rẹ́ ọmọ rẹ̀ lọ́rùn
Obinrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan ti di ẹni to n kawọ pọn rojọ niwaju Adajọ lori ẹsun pe o ṣeku pa ọmọ rẹ ẹni ọdun marun un.
Afurasi ọhun to n gbe labule Sabon Birni, to wa ni ijọba ibilẹ Gwarzo ni ipinlẹ Kano n jẹjọ ẹsun kan ṣoṣo, eyii to ni ṣe pẹlu ipaniyan.
Agbẹjọro ijọba, ọgbẹni Lamido Sorondinki, so fun ile ẹjọ pe afurasi naa hu iwa ọdaran naa lọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun.
- Ikú Williams Aanuoluwa lágbo òṣèré hú ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ síta
- Makinde ti sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí asekúpani Akinyele sálo mọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ ní àhámọ́
- Iná sọ lóòtọ́ láàfin mi, ṣùgbọ́n kò sí gìrí- Ooni Ile Ife
- Wo ibùdó arẹwà tí ọ̀pọ̀ èrò ń ya lọ ní Abuja
- Risikat, ìyá àwọn ọmọ olójú búlù tí bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́sẹ́ aṣojú lóge
Sorondinki sọ pe ọbẹ ni obinrin ọhun fi dubu ọmọ rẹ bi ẹni pa ẹran Ileya ni nnkan bi aago mẹjọ owurọ lọjọ naa lọhun.
Eyii to mu ko rọ ile ẹjọ naa pe ki wọn ṣe ayẹwo arun ọpọlọ fun arabinrin ọhun, gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin ọdun 2019.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ẹsun naa tapa si ofin to rọ mọ iwa ọdaran to wa ni abala 225 ninu iwe ofin.
Nigba ti wọn ni ko wa wi tẹnu rẹ, afurasi ọhun ni oun gba pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
Adajọ to n gbọ ẹjọ ọhun, Ibrahim Karaye, ti ni ki wọn gbe e lọ si ile iwosan awọn alaarun ọpọlọ fun ayẹwo.
Lẹyin naa lo sun igbẹjọ ọhun si ọjọ kẹjọ, ọsu Kẹwaa, ọdun 2020.