Soji Taiwo:Yekeen Ajileye ló gbé mi síta pẹ̀lú ìyá Gbónkán tí mo fi sọ pé olè ni ọkọ ajẹ́

Àkọlé fídíò, Soji Taiwo:Yekeen Ajileye ló gbé mi síta pẹ̀lú ìyá Gbónkán tí mo fi sọ pé olè ni ọkọ ajẹ́

Awọn agba tí a bá níwájú ló se ọbẹ̀ sílẹ̀ ti àwa òṣèré ìsinyi n gbé ka ina- Soji Taiwo

Gbajugbaja osere ni, Soji Taiwo ti ọpọ maa n pe ni O se, O se, Omo Banke gbalejo BBC Yoruba lalejo.

Soji Taiwo to saaba maa n ko ipa ọmọ ita ninu ere oniṣe ṣalaye fun BBC pe olorin ni Baba oun, Yomi Taiwo to jẹ elere juju, eyi to fihan pe ile ni oun ti ba iṣẹ yii.

O menuba ohun to bi orukọ rẹ Ose , Ose ọmọ Bankẹ.

Bawo ni Soji Taiwo se bẹrẹ ere oniṣe?

Soji Taiwo salaye ni kikun ere onise Alhaji Ajileye to gbe oun sita ati ipa ti oun ko nibẹ pẹlu iya gbonkan.

O gba awọn ọdọ to fi maa ṣere oniṣe ni imoran lati gbe igbesẹ to yẹ

O tun mẹnuba awọn ipenija ti o koju lẹni iṣẹ yii ki o to de ibi ti oun ti de.

Soji Taiwo salaye kikun nipa irinajo rẹ lati ibẹrẹ di isinyi.