June 12 Protest: Kìí ṣe Gómìnà Seyi Makinde ló ṣètò ìwọ́de June 12 ní Ibadan- Taiwo Adisa

"Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, onímọ̀ẹ̀rọ Seyi Makinde kọ́ ni ó ṣàgbékalẹ̀ ìwọ́de June 12 tó waye ni ipinlẹ Ibadan lọ́jọ́ Satide, lòdì sí ariwo tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú APC fi bọnu".

Akọwe ìròyìn gòmínà ìpińlẹ̀ Oyo Taiwo Adisa nínú àtẹ̀jáde tó fí léde ló ti fèsì sí àtẹ̀jáde àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC).

Adisa ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yìí kún fún ẹ̀tanú àti pé wọ́n ń gbìyànjú láti kó sọ̀ọ̀lọ̀ bọ gómìnà lọ́wọ́ ni nínú nǹkan tí kò mọ̀ nípa rẹ̀.

"Gbogbo ènìyàn ló mọ̀ pé kìí ṣe Ibadan nìkàn ní wọ́n ti ṣètò ìwọ́de June 12 bíkòse káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ mííràn."

Gẹ̀gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà ṣe lọ, lòdì sí nǹkan tí àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC sọ, Gòmìnà Seyi Makinde ko ṣe agbátẹru ìwọ́de ifèhònúhàn June 12 ní Ibadan.

Sààdédé ní gòmínà kó sí ọwọ́ àwọn olùwọ́de ní Orítamẹ́ta Osuntokun ní Bodija tó sì dúró láti bá wọn sọ̀rọ̀.

Gónmìnà ní alákoso ètò ààbò ìpínlẹ̀ rẹ̀, ó sì pọndandan kí ''o sọ̀rọ̀ tútù sí àwọn olùfẹ̀hónúhàn láti rí dájú pé ìrọwọ́rọ sì ni ìwọ́de wọn lọ, èyí saì ní nǹkàn tí gómìnà ṣe.

" Nǹkan tó yẹ kí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe ni láti gba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú láti fòpin sí àwọn ìwà tí kò yẹ àti bi wọ́n ṣe ń nàka àìtọ́ sí gbogbo iṣẹ̀lẹ̀ tí kò tó fiyè sí.

"Ó wà nínú àkọsílẹ̀ pé, kàkà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC yóò fi sowọ́pọ̀ láti ríi dáju pé ààbò tó yẹ wà fún ẹmí àti ohun iní àwọn ará ìlú ní ìpínlẹ̀, wọ́n kan n bu epo si inú ina tó n jò ni.

Bákan náà ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC ń hùwà àríjẹ nídìí mọ̀ndàrú.

" Ó ṣe pàtàkì kí APC jáwọ́ nínú àpọ̀n tí kò yọ̀ láti maa ro ibi ro ìpińlẹ̀ Oyo, láìpẹ́ láì jìnà àṣírí àwọn tó n da omi àláfía ìpińlẹ̀ Oyo rú yóò tú".