You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
June 12 Democracy Day: Ọmọ Nàìjíríà 10.5M la ti gbọ̀nṣẹ́ gbọ̀nyà kúrò lára wọn - Buhari
Ninu ọrọ ti aarẹ Muhammadu Buhari ba awọn ọmọ Naijiria sọ ni ayajọ ọjọ ijọba awa ara wa lo ti mẹnu ba a pe ijọba oun gbiyanju gidi lati yọ awọn ọmọ Naijiria kuro ninu iṣẹ.
Gẹgẹ bi Banki agbaye ṣe fi akọsilẹ sita, orilẹede Naijria wa lara awọn ti iye awọn to n jiṣẹ jiya ti pọ ju lagbaye.
Bẹẹ si ni lọdun 2019, Aarẹ Muhammadu Buhari ṣeleri lati rii pe o yọ eeyan ọgọrun miliọnu ọmọ Naijiria kuro ninu iṣẹ laarin ọdun mẹwa.
Aarẹ ni iṣẹ ṣi ku lati ṣe "a si n ṣa gbogbo ipa wa lagbami bi nkan ko ṣe tun to yii ti iye eeyan to wa ni Naijiria si n pọ sii ju iye awọn taa le fun niṣẹ lọ".
O fi kun un wipe bo tilẹ jẹ pe Covid-19 fi orilẹede Naijiria, awọn ṣi ni afojusun lati yọ eeyan ọgrun miliọnu kuro ninu iṣẹ laarin ọdun mẹwaa.
₦324bn la pín fún 136,000 oníṣòwò ké kè ké lásìkò ìgbélé Covid-19 - Buhari
Aarẹ orilẹede yii, Muhammadu Buhari ti ba awọn ọmọ Naijira sọrọ ni aarọ ọjọ Satide lati ki wọn ku ayajọ ọjọ ijọba awa ara wa to ko naa.
Ninu ọrọ rẹ, Buhari sọ nipa ọpọ aseyọri ti ijọba rẹ ti se lati igba to ti gori aga akoso orilẹede yii ni ọdun mẹfa sẹyin.
Lara awọn aseyọri ti Buhari mẹnuba ni awọn ipese awọn ohun eelo amayedẹrun si tibu tooro orilẹede yii
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ibi tí ìpalẹ̀mọ́ fún ìwọ́de June 12 dé dúró ní Nàíjíríà àti òkè òkun
- Ọ̀rọ̀ díẹ̀ ati ìgbésẹ̀ akin lá máa gbé báyìí lórí ọ̀rọ̀ Nàíjíríà - Obasanjo
- Wo ipa mánigbàgbé táwọn ààrẹ ní sáà ìjọba alágbádá kẹ́rin ṣe
- Wo àwọn ààrẹ alágbádá tó ti jẹ ní Nàìjíríà láti 1960 di àkókò yìí
- MKO Abiola, iṣẹ́ aṣẹ́gità ló fi bẹ̀rẹ̀ okoòwò
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá pín Nàíjíríà sí yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ
- Taiwo Akinkunmi, ọmọ Ibadan tó ya àsìá Naijiria
- Alimotu Pelewura, Ìyálọ́jà akọ́kọ́ l’Eko tó mi amúnisìn àti ìjọba tìtì
- Ìdílé márùn-ún tó gbajúmọ̀ fún òwò ẹrú nílẹ̀ Yorùbá
- Ogun Àgbẹ́kọ̀yà, ìjà òmìnira fáwọn àgbẹ̀ ni àbí ìfẹ̀míṣòfò?
Awọn koko ohun ti aarẹ Buhari sọ ninu ọrọ rẹ ree:
- Lati ọdun meji sẹyin, ọpọ ipenija lo ti ba wa ni Naijiria eyi ti ko ba ti jẹ orilẹede yii run paapaa lati ipasẹ eto aabo wa
- Mo ba awọn ẹbi ati ọrẹ awọn osisẹ agbofinro to padanu ẹmi wọn lasiko ti wsn n sisẹ oojọ wọn kẹkun
- Ẹ dibo yan mi lero pe maa fi opin si eto aabo to mẹhẹ ati iwa igbesunmọmi lẹkun ariwa Naijiria amọ ba se le wọn kuro nibẹ ti mu ki wọn fọn yika orilẹede Naijiria, eyi ta n koju bayii
- A ti n mọ awọn ọbayejẹ to n lo anfaani idarudapọ lati jẹ nidi mọdaru naa, ta si fi imu wọn jofin
- A ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu banki apapọ CBN lati mu idagbasoke ba eto ọrọ aje wa lati nnkan bii ọdun mẹfa ṣeyin
- Ni ẹka eto ọgbin, eto Anchor Borrowers Programme ti ṣe ti mu adinku ba iye ounjẹ ti a n ko wọle lati ilẹ okeere lati $2.23b to wa lọdun 2014 si US$0.59b ni ipari ọdun 2018
- Iye ti a fi n ko irẹsi wọle ja walẹ lati si $1 biliọnu lati $18.5 biliọnu to wa tẹlẹ
- Eto ti aṣẹ lati sọ ọrọ aje wa ji pada lẹyin ti arun Covid-19 mi gbogbo agbaye titi ti jẹ ki idagbasoke ba eto ọrọ aje wa pẹlu nnkan bii ida aadọrun, eto naa ṣi n lọ lọwọ
- Afojusun mi lati yọ ọgọrun un miliọnu eeyan kuro ninu kiṣẹ ni Naijiria ṣi lọwọ, idi rẹe ti a ṣe gbe eto National Social Investment Programme kalẹ, eyii to jẹ akọọ iru rẹ nilẹ Afrika ati eyii to tobi ju ni gbogbo agbaye, ko din miliọnu mejilelọgbọn eeyan to jẹ anmfani rẹ lọwọ yii
- Mo ti buwọlu eto adojutofo, eyii ti yoo mu adinku ba oṣi ni Naijiria
- Ko din ni miliọnju mẹjọ eeyan to n janfaani ẹgbẹrun un mẹwaa owo oṣu lati ọdọ ijọba yii
- Ni ipari ọdun 2020, banki idagbasoke Naijiria ti pi nnkan bii 324 biliọnu fun awọn oniṣowo kekeke ti iye wọn to 136,000 pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ile ifowopamọ kan
- Lasiko ajakalẹ aruhn Covid-19, a pin ẹgbẹrun marun un naira fun miliọnu kan eeyan
- A tun pin ẹgbẹrun lọna ogun naira fun awọn bii 750,000 eeyan, lẹyin naa ni a tun fun awọn 1.37 miliọnu eeyan ni ounjẹ lasiko konile-o-gbele Covid-19 labẹ eto CACOVID
- A ti buwọlu ileeṣẹ Infaco Plc, eyii ti yoo maa ṣe ọkọ ayọkẹlẹ ni Naijiria pẹlu owo idasilẹ ti ko din ni tiriliọnu marundinlogun naira
- Ijọba yii ti n kọ afara Niger keji lọwọ, a tun n ṣe atunṣe opopona marosẹ Eko si Ibadan, ati Abuja si Kaduna, to fi mọ Zaria si Kano
- Lara awọn aṣeyọri ijọba to wa lode yii ni bi a ṣe ṣi ọna oju irin reluwe Ibadan si Eko lọjọ diẹ sẹyin
- Miliọnu mẹwaa abọ eeyan ni a ti mu kuro ni iṣẹ ati oṣi.