Alimotu Pelewura: Akọni ajìjàgbara obìnrin, ìyálọ́jà àti olóṣèlú tó sun àtìmalé torí owó orí

Ti ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba nitori arọba gan an ni baba itan.

Eyi lo difa fawọn onkọwe kan ti wọn fi sọ pe, o yẹ ki awọn obinrin to n pe ara wọn ni ajìjàgbara mọ nipa itan awọn akọni obinrin kan, to ti wa saaju wọn.

Eyi ni wọn ni yoo mu ki awọn obinrin yii fi isesi awọn ajijagbara obinrin to ti siwaju, ti wọn ko si ba ilẹ jẹ, se awokọse rere.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn akikanju obinrin, ajijagbara ati Oloselu to dantọ̀ ni Iyalọ̀ja akọ̀kọ̀ nilu Eko wa gẹgẹ ba se ko iroyin aye rẹ jọ lati oju opo ayelujara Wikipedia.

Orukọ rẹ ni Oloye Alimotu Pelewura, ẹni to fi gbogbo ọjọ aye rẹ ja fun ẹtọ awọn obinrin papaa julọ niluu Eko.

Ohun to yẹ ko mọ̀ nipa akikanju obinrin to sun atimọle tori owo ori

A bi Oloye Alimotu Pelewura sí idile olorogun niluu Eko lọdun 1865, oun si ni akọbi awọn ọmọ ti iya rẹ bi.

Pelewura bẹrẹ owo ẹja tita lati igba ewe, ọwọ mọmọ rẹ lo ti jogun ba owo yii niluu Eko nigba naa.

Bo tilẹ jẹ pe Alimotu ko lọ sile iwe, Eledua fi ọpọlọ pipe jinki rẹ.

Ati pe itara to ni lori gbogbo ọrọ to ba nii ṣe pẹlu awọn obinrin jẹ ko ni ẹnu laarin awọn obinrin ẹgbẹ rẹ, ti wọn jọ wa ni ọja.

Ko pẹ ko jinna ni wọn dibo yan Oloye Pelewura gẹgẹ bi Iyalọja lọdun 1910, ti Oba Eshugbami, Eleko ti ilu Eko naa si tun fi joye.

Pelewura ṣiwaju awọn obinrin lọdun 1932 lati ṣe ifẹhonuhan tako agbekalẹ ofin ijọba akonilẹru ilẹ Gẹẹsi, to ni kawon obinrin maa san owo ori.

Wọn yan Pelewura gẹgẹ bí aṣoju awọn obinrin ninu igbimọ Ilu ti Oba Eko ṣe agbekalẹ rẹ.

Ni nnkan bi ọdun 1935, Pelewura ṣagbatẹru iwọde tako bi wọn ṣe gbe ọja Ereko lọ si agbegbe Oluwole.

Pelewura atawọn obinrin mii gbiyanju lati dena gbigbe ọja naa kuro nibi to wa, eyi to jẹ ki wọn ju sí atimọle.

Awọn obinrin to n ta ọja niluu Eko ṣewọde titi ti ijọba fi tu Pelewura at'awọn obinrin mii latimole silẹ.

Lọdun 1940, ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi tun ṣe agbekalẹ owo ori tuntun fawọn obinrin ti wọn ba n gba ju aadọta pọun lọ.

Awọn obinrin kii san owo ori tẹlẹ nilẹ Yoruba, eyi jẹ ko ṣe ajeji sí wọn.

Pelewura at'awọn obinrin mii tun dide lati ṣe ifẹhonuhan tako igbesẹ naa tori o jẹ ajeji sí wọn.

Paapaa nitori bi ọrọ aje ṣe dẹnu kọlẹ nigba naa pẹlu airiṣẹ ṣe ọpọ eeyan nitori ogun agbaye to n lọ lọwọ lasiko naa.

Pelewura wọ agbo oṣelu lọdun 1939, o ṣi di ọkan lara ọmọ igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu NUYD, ẹgbẹ to n ṣe aṣepọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu NNDP.

O maa n sọrọ nigba mii gẹgẹ bi olori lasiko ipolongo fawọn oludije ẹgbẹ oṣelu NNDP bo tilẹ jẹ pe awọn obinrin ko lanfaani lati dupo nigba naa.

Pelewura tun jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ Nigerian Women's Party, NWP ti oloye Oyinkansola Abayomi da silẹ.

Lasiko ogun agbaye ẹlẹẹkeji lọdun 1941, gbogbo nkan lo wọn gogo nitori ọda ounjẹ.

Èyí mu ki ijọba ṣe agbakalẹ eto lati maa dari iye tawọn eeyan maa ta ọja wọn.

Pelewura at'awọn akẹgbẹ rẹ tako eto naa, wọn ni ko ni jẹki awọn ri ere jẹ to.

Lọdun 1947 ni wọn fi Pelewura jẹ oye Erelu nitori bi o ṣe n ṣoju awọn obinrin.

Amọ, iku ko dọjọ, arun ko doṣu, igi to tọ kii pẹ nigbo, Pelewura jade laye lọdun 1951.

Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo peju pesẹ sibi eto isinku rẹ lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un.

Ẹkọ ti igbe aye ati aseyọri Alimotu Pelewura kọ wa

  • Ẹkọ akọkọ ni pe aikawe ko ni ka ma debi giga nile aye
  • Ẹkọ keji ni pe ko si iyatọ laarin ọpọlọ ti Ọba Oke fun ọkunrin ati obinrin, ko si si obinrin ti ko le se aseyọri to ba pinnu lati se bẹẹ
  • Itan aye Alimotu Pelewura tun kọ wa lati maa sa ipa wa lati fi ipa rere lelẹ ni awujọ ti a ba wa
  • Itan yii tun kọ wa pe ka maa sọrọ soke lori ohun ti a ko ba fara mọ boya ọkunrin ni ẹ abi obinrin.