NSCDC mú ọkùnrin tó ń bá ọmọ ọdún mẹ́sàn án tó jẹ aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀ ni Kwara

Ọwọ́ tẹ bàbá ẹni ọdun 60 níbi tó ti n bá ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lòpọ̀.

Ajọ ẹṣọ alaabo abo ara ẹni, laabo ilu, Civil Defence nipinlẹ Kwara , ti mu ọkunrin ẹni ọgọta ọdun kan to fi ipa ba ọmọ ọdún mẹsan lo pọ.

Iroyin sọ pe Jerimiah Oyedoki fi ipa ba ọmọdebinri naa to jẹ ọmọ alajọgbele rẹ ni ilu Kaiama nijọba ibilẹ Kaiama nipinlẹ naa.

Ileesẹ iroyin ori ayelujara, The Guide sọ pe nibi ti Oyedoki ti n ba ọmọ naa lo pọ̀ ni ọwọ awọn òbí ọmọ naa ti tẹ.

Eyi to mu ki wọn o pariwo, ti wọn si fi ọrọ to ajọ NSCDC leti.

Agbenusọ ajọ naa nipinlẹ Kwara, Babawale Afolabi sọ fun awọn akọroyin pe ni nkan bi aago márùn-ún àbọ̀ irọlẹ ni Jerimiah Oyedokun to n gbe ni agboole Ileloja, Kaiama fi ipa ba ọmọ naa lo pọ.

O ni aadọta Naira ni afurasi naa sọ pe oun fi tan ọmọbìnrin naa.

Wọn ti gbe ọmọ naa lọ si ileewosan ijọba ni Kaiama fun awọn ayẹwo to peye.

Bakan naa ni Ọgbẹni Afolabi sọ pe ẹjọ ọkùnrin naa ti wa ni olu ileesẹ ajọ NSCDC, ti wọn o si gbe e lọ sile ẹjọ laipẹ.