You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Muri Thunder: Àfojúsùn mi ni láti gba Grammy gẹ́gẹ́ bíi olórin Fuji
Gbajugbaja olorin Fuji, Alhaji Muri Alabi Thunder, ti ọpọ mọ si Muri Thunder ti sọ pe ko si ija kankan laarijn oun ati Saheed Osupa.
Muri Thunder lo tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.
Ṣaaju ni ọkan lara awọn ololufẹ olorin Fuji naa ti kọkọ bere loju opo Facebook ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba ki eto naa to bẹrẹ nipa ohun to fa ija laarin oun ati Osupa Saheed.
Nigba to n fesi, Muri Thunder sọ pe ọga ati ẹni ti oun n wo loke ni Saheed Osupa jẹ, kii ṣe ẹni ti oun le maa sọrọ abuku si.
- Ìpínlẹ̀ Èkìtì ṣetán láti gbà àlejò ìwọ́de ìlànà Ọmọ Odua
- Ìpínlẹ̀ Èkìtì ṣetán láti gbà àlejò ìwọ́de ìlànà Ọmọ Odua
- À ń ṣe ara wa ni Bí a bá kọ̀ láti máa lo egbòogi igbó ní Naijiria - Akeredolu
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí 'twitter' tíjọba dá dúró ní Nàijíríà yóò ṣe kan ọ
- 'Kò sí ààtò fún òfin Sharia àti ẹtọ àwa ẹlẹsìn Islam nínú Oduduwa Republic, a ò gbà!'
- Wo ohun ti yóò ṣẹlẹ̀ sí obìnri tó bá fi ojú rí Orò
- Ilẹ̀ Yorùbá kìí ṣe ibi kátàkárà fún yín, ẹ̀yin àgbà tẹ ń gbárùkù ti ọ̀dọ́ lẹ́yìn láti máa da ìlú rú ẹ sọ́ra - Ẹgbẹ́ YWG
- Àwon ẹlẹ́ja ṣe ìfẹ̀hónúhàn nílùú Akure nítorí ọ̀kan nínú wọn tí ilé wó pa
Bo tilẹ jẹ ko sẹ nigba ti atọkun eto naa bere lọwọ rẹ nipa ija ti wọn ni o wa laarin oun ati Saheed Osupa ṣaaju.
O ni "Ibaṣepọ emi ati King Saheed Osupa gun rege ko si si ija kankan laarin wa."
"Gbogbo ohun ti awọn eeyan n sọ yẹn ti di afiṣeyin ti eegaun n fi aṣọ nitori ọrọ naa ti do ohun igbagbe."
- Olorì Damilola fi èpè ránṣẹ́ sí 'bàbá' rẹ̀ to ní kò padà sọ́dọ̀ Aláàfin
- Ọ̀gá àgbà NECO papòdà- Kà nípa bí Ọjọ́gbọ́n Obioma ṣe kú
- Wo ìdí tó fi ṣeéṣe kí ìjọba àpapọ̀ ó kéde àkọ̀tun ìséde n'ipínlẹ̀ Eko
- Nǹkan kò burú tó báyìí ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn tí mo kọrin pé kí Ọlọ́run bá wa tún Nàijíríà ṣe- Funmi Aragbaye
Lasiko to n fẹsi si ohun to ṣẹlẹ to fi sọko ọrọ si Saheed Osupa ninu awon orin rẹ kan.
Muri Thunder sọ pe "Kii ṣe pe emi ati Osupa ni ija tẹlẹ, ohun to ṣẹlẹ nigba yẹn, ija gbogbogbo ni."
Gbajumọ onifuji naa ṣalaye pe gbogbo olorin Fuji lo n kọ orin bu ara wọn lọdun naa lọhun, kii ṣe pe oun mọọmọ sọ oju si Saheed Osupa lara.
Yatọ si ọrọ Saheed Osupa, Muri Thunder tun sọ pe irẹpọ to dan mọran lo wa laarin oun ati gbajugbaja olorin Fuji miran, iyẹn Wasui Alabi Pasuma.
Nigba to n sọrọ lori bi irinajo rẹ ṣe ri nidii iṣẹ orin fuji, Muri Thunder sọ pe wọn bi iṣẹ orin mọ oun ni.
Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko kọ iṣẹ naa lọdọ ẹnikẹni, o ni lara awọn olorin ti oun gbe oṣuba kare fun ni Saheed Osupa, oun si ti ba oniruru olorin ṣiṣẹ papọ.
Ni ti afojusun rẹ fun ọjọ iwaju, Muri Thunder sọ pe yatọ si oniruru ami ẹyẹ ti oun ti gba tẹlẹ, yoo wu oun lati gba ami ẹyẹ Grammy gẹgẹ bii onifuji.