Funmi Aragbaye Nigeria Gospel: Kò burú tó báyìí ní ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn tí mo kọrin pé kí Ọlọ́run

Gbajugbaja akọrin ẹmi ti o tun jẹ aare ẹgbẹ awọn olorin ẹmi ni Naijiria, Arabinrin Funmi Aragbaye ti sọrọ lori bi orilẹede Naijiria ṣe le koko to yii ati iran to ti ri nipa bi Naijiria yoo ṣe ri lonii.

O ṣe alaye wi pe awọn iṣipaya ti Ọlọrun fi han ati irora ti awọn ọmọ Naijiria n ke ni nnkan bii ọgbọn ọdun o le sẹyin lo ṣe okunfa orin ti o pe akọle rẹ ni "Ọlọrun Igbala".

Ninu ọrọ ti o ba BBC Yoruba sọ, Aragbaye ni awọn nnkan ti o n ṣẹlẹ lorilẹ-ede Naijiria ni ọgbọn ọdun sẹyin ti awọn eeyan ilu fi n ke ibosi pe ilu le ko ṣee fi we mọ.

O ni awọn nnkan to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii, nitori a le ṣe apejuwe rẹ wi pe awọn eeyan n ri ẹran jẹkọ nigba naa ni.

Olorin ẹmi naa fi kun ọrọ rẹ wi pe, "a ṣe nnkan kan ko wọn nigba ti mo kọrin wi pe ohun gbogbo di wiwọn o, pe ki Oluwa ma fi ogun ba wa wi ki o si ma fi iyan ba wa ja ni Naijiria".

Aragbaye ni: Lara ọrọ inu orin naa sọ wi pe, "ọrọ oṣelu ma d'ọwọ rẹ, ma jẹ ki awọn olori ko wa ṣina".

Aarẹ awọn olorin ẹmi naa ṣe alaye wi pe lara nnkan to sun orilẹ-ede yii de ibi ti o wa bayii ni pe nnkan ti awọn olori wa maa ri jẹ lo mu wọn dije du ipo.

O ni, "eyii lo si ṣokunfa wahala ẹlẹyamẹya ti a fi ri awọn eeyan kan ti wọn n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, botilẹ jẹ wi pe ẹnu Yoruba naa o konu".

Aragbaye tẹsiwaju wi pe, "Mo ti lọ kaakiri agbaye, mo ri bi awọn adari wọn ṣe ṣakoso ilu yẹn.

Mo wa woo pe Naijiria nibi ti a ti ni gbogbo nnkan ti o le sọ Naijiria di orilẹede nla.

Ṣugbọn a o ni awọn olori ti o dara. Imọtara ẹni nikan lo wa lọwọ awọn olori wa. Ko si ẹmi Ọlọrun bẹẹ sini wọn ko ni ẹri ọkan".

Akorin ẹmi Funmi aragbaye ni, "lati ọjọ ti mo ti wa laye, Naijiria ko tii le koko to eleyii. Igba ti awọn ologun wa nibẹ a n kigbe, a ṣe a n fi ẹran jẹkọ ni. Ẹ wo ibi ti a de lonii".

Funmi fi kun ọrọ rẹ wi pe yatọ si awọn olori orilẹede yii, gbogbo ọmọ Naijiria lo ti ṣẹ ni ọna kan tabi omiran, paapaa julọ awọn ti o ta ọjọ iwaju wọn fun owo kekere ti wọn rigba lọwọ awọn oloṣelu.

O ni igba ti ogun ba le nikan ti awọn ọmọ Naijiria maa n gba adura. Ti ogun ba ti ṣẹ, a o tun gbọjẹgẹ.

Ọna abayọ sini wi pe ki a ma dẹkun adura nitori pe "agbaku ni adura".

Ki olukuluku si fi si adura wi pe bi ti wu ki o le to, ki o ma ṣe le mọ wọn.