Ibadan killing, Linus Onwuamana: Àwọn jàndùkú agbébọn yìnbọn pa ọkùnrin oníṣòwò kan nílùú Ibadan

Ọrọ eto abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria ti n burẹkẹ si, lẹyin tawọn janduku agbebọn tun ṣekupa ọkunrin oniṣowo kan niluu Ibadan.

L'ọjọ Aiku ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ fi idi ọrọ naa mulẹ lori ipapoda Arakunrin Linus Owuamanam, oniṣowo ti awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko damọ yinbọn pa.

Iroyin sọ wi pe ni nnkan bi i aago mẹjọ alẹ ọjọ Abamẹta ni awọn olubi ẹda naa gbẹmi Onwuamana.

Oniṣowo naa ni wọn sọ wi pe o n wa ọkọ akẹru kan lọ lopopona Mọkọla si Sango nilu Ibadan lasiko ti o se kongẹ iku ojiji.

Lẹyin ti wọn yinbọn fun un tan, awọn agbebọn naa tun fi nnkan gun un ni aya lati riidaju ko ru ikọlu naa la.

Bẹẹ si ni ko si ẹnikẹni ti o mọ ibi ti ẹnikeji to n ba oloogbe rin irinajo lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ wa bayii.

Ẹni kan ti o n kọja lọ ti o si ri oloogbe naa ninu agbara ẹjẹ lo fi iṣẹlẹ naa to awọn oṣiṣẹ rẹ leti.