You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yoruba Nation agitators: Àwọn ajìjàngbara Yorùbá Nation fipá ṣí bọ́dà Idiroko
Awọn ajijangbara to n pe fun Yoruba Nation fi ipa ṣi ibode Naijiria si Benin Republic ni Idiroko lọjọ Satide.
Wọn ni ọna ti ṣi pe kawọn eeyan maa ko ounjẹ atawọn nnkan mii wọlu lọpọ yanturu
Amọ, awọn ẹṣọ aṣọbode to n ṣọ ibode naa dawọn lọwọ kọ.
- Sunday Igboho bẹ̀bẹ̀ lórí ìkùnsínú tó ń wáyé nípa ìwọ́de l‘Ekiti
- ''Ẹ ó ríjà Ọba, tí ẹ bá gbìyànjú láti fọ́wọ́ kan Sunday Igboho''
- Agbébọn yabo ilé Sunday Igboho ní òru mọ́jú
- Arúmọjẹ lásán ni lọkọ-láya tí èmi àti Cute Abiola jọ́ ń ṣe tẹ́lẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ti dé- Adeherself
- Tí Benue kò bá ní Sunday Igboho tIẹ̀, ìṣekúpaní yóò tẹ̀síwájú - Reno Omokri
Ọdun 2019 ni ijọba apapọ gbe awọn ibode oriilẹ si Naijiria tipa ti wọn ṣi bẹrẹ si ni ko gbogbo ọja wọle lori omi nikan.
Ninu fidio kan to wa lori ayelujara ni ọkunrin kan ti n yinbọn soke tawọn eeyan to wa nibẹ ṣi n dunnu.
Ọpọ lo n sọ ninu fido naa pe kawọn ẹṣọ aṣọbode atawọn sọja wa yinbọn ma wọn ti wọn ba to bẹẹ.
A gbọ wi pe awọn ajijagbara naa ba geeti ibode Idiroko jẹ, ti wọn si n pariwo ''a ti ṣi ibode Idiroko.''
Koda, wọn lu ọkunrin kan to gbiyanju lati ṣe fidio iṣẹlẹ naa pẹlu foonu rẹ laluki.
Agbẹnusọ ileeṣẹ aṣọbode agbegbe Idiroko, Hammed Oloyede to fidi ọrọ naa mulẹ ṣalaye pe awọn ajijangbara Odua Nation ko ṣe ikọlu sawọn ẹṣọ aṣọbode.
Ọgbẹni Oloyede ni awọn ajijangbara naa kan n ṣe ti wọn ni, o ni ko si iyọnu kankan.
O fikun ọrọ rẹ pe awọn eeyan naa gbiyanju lati kọlu awọn oṣiṣẹ aṣọbode ṣugbọn awọn da wọn lọwọ kọ.