Mali Coup: ECOWAS ti fi òfin de àárẹ Mali, wọ́n ní dandan ni kó dá ìjọba alágbádá padà

Awọn adari ajọ Ecowas da Mali duro lẹyin iditẹgbajọba to waye nibẹ.

Iditẹgbajọba to waye ni Mali lọsẹ to kọja, ti mu ki ajọ Economic Community of West African States, Ecowas, fi ofin de orilẹ-ede naa.

Iditẹgbajọba naa to sọ Colonel Assimi Goita di aarẹ tuntun, ni ẹlẹẹkeji to waye laarin oṣu mẹ́sàn-án.

Yatọ si fifi ofin de Mali, àwọn adari Ecowas tun sọ pe o gbọdọ yan Olootu ijọba alagbada ni kiakia.

Nibi ipade to waye lori ọrọ Mali ni Ghana lọjọ Aiku, ni wọn ti sọ fún aarẹ ologun tuntun ọhun to n na wa nibi ipade.

Bakan naa ni wọn tun fẹ ki Colonel Assimi Goita ṣe eto idibo ko to o di oṣu Keji, ọdun to n bọ.

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere ni Ghana, Shirley Ayorkor Botchwey sọ fun awọn akọroyin pe o ṣe pataki ki Mali duro daadaa nitori wahala àwọn agbesunmọmi to n waye nibẹ.

"Nitori naa lo ṣe ṣe pataki pe ki wọn o tẹle ilana gbigbe ijọba fun alagbada laarin oṣu mejidinlogun."

Colonel Goita gun ori aga isakoso ijọba lẹyin to pàṣẹ pe ki wọn o mu aarẹ fidihẹ, Bah Ndaw ati Olootu ijọba, Moctar Ouane, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un.