Well Poisoning: Wo ìdí tí àgbẹ̀ kan, Mohammad fi da májèlé sínú kànga mẹ́sàn án táwọn èèyàn ń mu

Ọkunrin kan to n ṣiṣẹ agbẹ, Mohammad Mohammad ti kò si gbaga ọlọpaa lori ẹsun pe o da majele si kanga mẹsan an labule Kasesa nipinlẹ Yobe.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Dungus Abdulkarim lo fidi ọrọ yii mulẹ niluu Damaturu.

Lọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu karun un ọdun 2021 yii ni ọwọ ọlọpaa tẹ Mohammad to jẹ ẹni ọdun mẹẹdọgbọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọlọsin ẹran naa maa n lo omi ọhun fawọn ẹran wọn.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe awọn ṣe ayẹwo lori awọn omi inu kanga naa eleyii to ṣafihan pe ẹnikan ti da oogun apakokoro sinu wọn.

"Lẹyin naa ni a mu Mohammad afurasi to ṣiṣẹ ọhún, yoo si foju ba ileẹjọ laipẹ.

Muhammad si jẹwọ pe lootọọ loun da oogun sinu awọn kanga naa, amọ ohun ti oun fẹ ṣe ni lati maa le jẹ ki awọn darandaran da ẹran jẹ oko oun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ṣí n gbiyanju lati fọwọ ofin mawọn ọlọsin ẹran to dẹran jẹ oko bakan naa," Abdulkarim ṣalaye.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa rọ awọn agbẹ at'awọn darandaran lati yago fun iwa to le da wahala silẹ.