Igangan Massacre; Orílẹ̀ède 174 káàkiri àgbáyé ní ìwọ́de Yoruba Nation yóò tí wáyé ní June 12

Ọkan lara ẹgbẹ ọmọ Yoruba to gajulọ lagbaye, Yoruba One Voice ti kede pe awọn yoo ṣe iwode kaakiri agbaye ni Ọjọ Ayajọ June 12 lati pe fun idaduro orilẹede Yoruba kuro ni ara Naijiria.

Alaga ẹgbẹ naa, Abilekọ Ọmọladun Orolugbagbe ni ẹgbẹ naa ti pari gbogbo eto ti wọn nilo ki ayẹyẹ naa fi le waye.

Ẹgbẹ Yoruba One Voice fikun kaakiri awọn orilẹede to wa lagbaye to fi mọ orilẹede mẹrinlelaadọsan ni iwode naa yoo ti waye.

Orolugbagbe ni asiko ti to fun gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba lati dide ki wọn fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn to n pe fun idaduro orilẹ-ede Yoruba, ki o le ṣeeṣe.

Orolugbagbe fikun pe ko dun mọ awọn ọmọ ilẹ Yoruba kaakiri agbaye ninu pẹlu iṣekupani ọlọgọọrọ to n waye lojoojumọ nibẹ.

''June 12 jẹ ọjọ kan pato ninu itan awọn ọmọ Yoruba ti wọn dibo lati gba ara wọn silẹ lọw ijọba ologun kaakirii Naijiria.

''Nitori naa ni a se fẹ ṣe iwode oun ni ọjọ naa ki gbogbo aye le ri wi pe awọn ọmọ Yoruba to wa lokeere naa fi ọwọ si idaduro ilẹ Yoruba kuro lara Naijiria.''

Ẹgbẹ Yoruba One Voice naa fi ẹhọnu han si ijọba apapọ lori aibikita pẹlu ipaniyan to n waye ni ilẹ Yoruba ati ni orilẹede Naijiria, ti wọn si sapejuwe ti eleyii to n ṣẹlẹ ni ilu Igangan ni ijọba ibilẹ Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ.

O fikun wi pe iroyin to tẹ awọn lọwọ ni wi pe awọn ọmọogun Naijiria ti wọn wọ aṣọ araalu lo hu iwa ọdaran naa, ti ko si si ẹni to le e tọka si wọn wi pe awọn ni wọn ṣiṣẹ naa.

Ẹgbẹ naa ni awọn ko ni igbagbọ ninu orilẹede Naijiria mọ ati ijọba to wa lode yii nitori wọn ko ri nkankan ṣe si ipaniyan, ijinigbe ati ọpọlọpọ iwa ọdaran to n waye lojoojumọ ni Naijiria.