TB Joshua: Ariwo sọ lórí ayélujára nípa Pásítọ̀ tó ní ìṣẹ́gun ńla ni ikú wòlíì náá jẹ́ fún òun

Yoruba ni ba ku laa dere, eeyan ko sunwọn laaye, ti wọn si maa n koro oju si ki eeyan tabuku ẹni to ba ti ku.

Idi ree ti ọpọ eeyan se ta gba Pasitọ kan lorilẹede Kenya to n fo fayọ nitori wolii TB Joshua jade laye.

Jackson Seyonga, tii se pasitọ agba fun ijọ Christian Life to wa nilu Kampala lo n yọ lori iku wolii naa ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan.

Ni kete ti Pasitọ Seyonga gbọ nipa iku Joshua lọjọ Aiku lasiko isin to n lọ lọwọ nile ijọsin rẹ, eyi ti wọ̀n n fi ẹrọ ayaworan ka silẹ, lo n fo fayọ pe eeyan ibi jade laye.

"Wolii TB Joshua ti ku, ẹ ke Haleluyah, alẹ ana lo ku. Se bi mo sọ fun gbogbo yin pe Ọlọrun nikan lo le bori ogun ni orukọ Jesu.

Mo ri iku rẹ bii isẹgun fun mi."

Pasitọ naa wa sọ nipa ọpọ eeyan to ku nibi isẹlẹ ile to wo ninu ijọ Sinagogu lọdun 2014, ninu eyi ti ọpọ ọmọ ilẹ okeere wa nibẹ.

"O ro pe aye toun se iyebiye ju aye ẹgbẹlẹgbẹ eeyan to ku ninu isẹlẹ naa lọ. Ki lo mu ko ro pe oun le pa ọpọ eeyan tori pe o fẹ se irubọ?

O fikun pe ajẹ nla to n gba ọpọ ẹmi eeyan ni TB Joshua to jade laye naa, ẹsan lo de fun.

Amọ ọpọ eeyan lo ti n fesi lori fidio naa, ti wọn si n sọ oko ọrọ pada si Pasitọ Seyonda fun iwa ẹsẹ to hu naa.

Lara awọn eeyan to si n tako isẹlẹ yii ni Daddy Freeze wa.

Daddy Freese sọ oko ọrọ pada si Pasitọ Seyonga lori bo se n yọ iku TB Joshua

Gbajumọ onwoye kan lori ayelujara, Ifedayo Akinrinde, ti ọpọ eeyan mọ si Daddy Freeze ti wa fesi pada fun ojisẹ Ọlọrun to n yọ iku akẹẹgbẹ rẹ naa.

Ninu fidio miran to gbe sita l;oju opo Instagram rẹ, Daddy Freeze ni se ni ara oun n gbọ lati gbọ pe Kristiẹni le yọ lori iku ẹnikan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni o ti foju han pe ọta nla ni awọn mejeeji loju aye amọ eyi ko fun Pasitọ naa lẹtọ lati maa yọ lori iku ẹlomiran.

Freeze wa tọka si awọn ẹsẹ inu iwe mimọ Bibeli, Iwe Owe ori Kẹrinlelogun ẹsẹ ikẹtadinlogun ati ikejidinlogun, to ni ka mase dunnu si isubu ẹlomiran.

O ni ọkan oun rẹwẹsi lori fidio naa, ti oun ko si gbagbọ nipa ohun ti eti oun n gbọ.

"Kii se iwa ọmọ Ọlọrun lati maa yọ lori iku ọta ẹni, nitori a ko kọ wa bẹẹ.