You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
TB Joshua ló san owó iṣẹ́ abẹ ojú tí mo ṣe nílùú London - Dele Momodu
Alaga ati oludari ileeṣẹ iwe iroyin Ovation, Oloye Dele Momodu ti sọ iriri rẹ nipa pasitọ ijọ Synagogue Church of All Nations, SCOAN, to di ologbe, TB Joshua.
Dele Momodu lo sọ ọrọ naa lasiko to ṣabẹwo ibanikẹdun si ẹka ijọ SCOAN niluu Eko.
Nibẹ lo ti sọ pe TB Joshua lo san owo iṣẹ abẹ oju ti oun ṣe lọpọ ọdun sẹyin.
Gbajumọ akọroyin naa ṣalaye nipa bi irinajo rẹ ati oloogbe naa ṣe bẹrẹ to fi mọ igba ti o san owo iṣẹ abẹ abẹ oju ti o ṣe.
- Alaseyori kọ́ ló ni orin "Oniduro Mi", àmọ́ ìdí tí mi ò ṣe bá a jà pé ó jí orin mi kọ nìyìí - Tolu Adelegan
- Kí ló fa gbas-gbos láàrin Tope Alabi àti Olórin tó kọ "Oniduro Mi e se"?
- Kílódé tí ariwo ìgbéyàwó Toyin Lawani ṣe fa orí ayélujara ya?
- Israel Adesanya dúró sókè ténté nínú ìjàkadì UFC lẹ́yìn tó fẹ̀ṣẹ́ fọ́ Vettori lẹ́nu
- Kìí ṣe Gómìnà Seyi Makinde ló ṣètò ìwọ́de June 12 ní Ibadan kò sì bá wọn kópa - Taiwo Adisa
O ni "Mo ni ipenija oju lasiko kan mo si ṣe iṣẹ abẹ oju naa niluu London, lẹyin iṣẹ abẹ ọhun ni nọmba kan pe mi ti ẹni to wa lodi keji ipa naa si sọ pe Alagba, wọn sọ fun mi pe oju n dun yin, yoo wu mi lati san owo iṣẹ abẹ oju yin."
"Mo sọ fun pe mo ti san owo isẹ abẹ oju naa ṣugbọn o faake kọri pe dandan ni ki oun san owo iṣẹ abẹ oju naa."
Mo kọ fun lati san owo naa ṣugbọn lẹyin ti ko jawọ lori sisan owo ọhun ni mo gba si lẹnu, ti mo si fi nọmba apo ile ifowopamọsi ranṣẹ si."
Dele Momodu ṣalaye nipa igba akọkọ ti oun pade TB Joshua ati bo ṣe maa n ṣe aanu fun ọpọ eeyan.
Bakan naa lo ṣalaye nipa ohun ti TB Joshua sọ fun lasiko to n du ipo Aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọdun 2011.
O ni "Emi ati TB Joshua pade ninu ile kan niluu New York lọdun naa lasiko ti mo n du ipo Aarẹ."
"O sọ pe mi o ni jaweolubori ninu eto idibo naa o, ṣugbọn mo maa jẹ ọkan gboogi lara awọn alẹnulọrọ lorilẹ-ede Naijiria."
Dele Momodun pari ọrọ rẹ pe oun ati TB Joshua sunmọ ara wọn to bẹẹ ti to fi jẹ pẹ ọpọ awọn eeyan lo n pe oun lẹyin iku rẹ.
Lẹyin naa lo gbadura ki Ọlọrun tẹ ẹ si afẹfẹ rere.
Ọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni TB Joshua jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta, ọpọ eeyan ni Naijiria lo ṣedaro rẹ gẹgẹ bii akọni onigbagbọ ati ẹlẹyinju aanu.
Aarẹ Muhammadu Buhari, awọn gomina ni Naijiria atawọn alẹnulọrọ laarin ilu lo ti fi ọrọ ikaanu ranṣẹ si awọn ẹbi rẹ.
Ẹwẹ, Oriade ilu ti oloogbe naa ti wa, iyẹn Ọba Yisa Olanipekun, to jẹ Zaaki ti ilu Arigidi-Akoko ni ipinlẹ Ondo ti sọ pe yoo wu awọn ko jẹ pe inu ilu naa ni wọn sin TB Joshua si.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
A kò ní ṣe ètò ìsìnkú TB Joshua ní bòńkẹ́lẹ́ - Evelyn Joshua
Aya oloogbe Temitope Balogun Joshua, to jẹ oluṣọagutan agba ijọ Synagogue Church of All Nations, SCOAN, ti sọ pe awọn ko ni ṣe eto isinkun oloogbe naa ni bonkẹlẹ.
Evelyn Joshua lo sọ ọrọ naa lasiko ti gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ṣabẹwo si ijọ naa to wa lagbegbe Ikotun, niluu Eko.
Arabinrin ọhun ni iku ọkọ oun ko ya oun lẹnu nitori o ti maa n sọ tẹlẹ pe inu iṣẹ iranṣẹ ni oun yoo ku si.
- Kí ló fa gbas gbos láàrin Tope Alabi àti Olórin tó kọ "Oniduro Mi e se"?
- Ọmọ Nàìjíríà 10.5M la ti gbọ̀nṣẹ́ gbọ̀nyà kúrò lára wọn - Buhari
- Kìí ṣe Gómìnà Seyi Makinde ló ṣètò ìwọ́de June 12 ní Ibadan kò sì bá wọn kópa - Taiwo Adisa
- Kò ní sí ìrìnàjò Hajj fáwọn ọmọ Nàìjíríà àt'orílẹ̀èdè míràn lọ́dún yìí
- Wo ohun tó mú kí àyájọ́ June 12 ṣe pàtàkì fún Nàíjíríà
- Ọwọ́ tẹ Kabiru tó ṣá ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ bí màlúù ní Apomu
O ni "Kii ṣe ohun iyalẹnu fun mi, gẹgẹ bi gbogbo wa ṣe mọ pe o ṣi kopa ninu isin lọjọ to dagbere faye."
Evelyn ṣalaye siwaju si pe iṣẹlẹ iku ọkọ oun ko ṣẹyin Ọlọrun ati pe ohun gbogbo ni akoko wa fun.
O sọ pe "Gẹgẹ bi ọkọ mi ṣe maa n sọ ni gbogbo igba pe idi iṣẹ iranṣẹ yii ni oun ti di gbajumọ, idi iṣẹ naa si ni oun yoo ku si."
Gomina ipinlẹ Eko juwe iku iranṣẹ Ọlọrun naa gẹgẹ bii adanu nla fun awọn ẹbi rẹ, ipinlẹ Eko, paapaa awọn eeyan agbegbe Ejigbo si Ikotun, ati si awọn ọmọ ijọ SCAON kaakiri agbaye.
Ọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni TB Joshua jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta, ọpọ eeyan ni Naijiria lo ṣedaro rẹ gẹgẹ bii akọni onigbagbọ ati ẹlẹyinju aanu.
Aarẹ Muhammadu Buhari, awọn gomina ni Naijiria atawọn alẹnulọrọ laarin ilu lo ti fi ọrọ ikaanu ranṣẹ si awọn ẹbi rẹ.
Ẹwẹ, Oriade ilu ti oloogbe naa ti wa, iyẹn Ọba Yisa Olanipekun, to jẹ Zaaki ti ilu Arigidi-Akoko ni ipinlẹ Ondo ti sọ pe yoo wu awọn ko jẹ pe inu ilu naa ni wọn sin TB Joshua si.
- Àṣìgbé ọmọ wọ́ọ̀dù ni Seyi Makinde - Àgbààgbà PDP l‘Oyo ka ẹ̀sùn sí gómìnà l'ẹ́sẹ̀
- Kìí ṣe jàgídíjàgan ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Naijiria - Ohaneze, Mefor, Briggs
- Ọwọ́ tẹ bàbá ẹni ọdun 60 níbi tó ti n bá ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lòpọ̀
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tó fọ́ ààrẹ Faranse létí
- "Bí Buhari kò bá dáàbò bo aráàlú, Sunday Igboho àtàwọn èèyàn míì yóò ṣé"