FCMB Marriage Scandal: Báńkì náà ní òun ń ṣe ìwádìí lọ́wọ́ lórí ẹ̀ṣùn ọgá agbà rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilé ifowópamọ́ First City Monument Bank (FCMB) ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ni wó ẹsun ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n fi kan àdárí ilé ifowópamọ́ náà, Adamu Nuru.

Láti bi ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni ìròyìn kan ti ń jà rànìn-rànìn lórí ayélujára, níbi ti wọn ti ṣe àfihan fótó ti ọgá àgbà banki naa, Adamu Nuru àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ mẹji wà.

Àlàyé tó tẹ̀lé fọ́nrán náà ni pé, ọgá Adamu ń ni àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ọmọbinrin kan tó n jẹ́ Moyo Thomas, Moyo yìí jẹ òṣíṣẹ́ ilé ìfówópámọ́ náà tó si ní ọkọ, sùgbọ́n ó n yan ọ̀gá rẹ̀ ni àlè.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìròyìn sọ pé, lẹ́yìn ti ọkùnrin náà padà si orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló déde yí subú lẹnu àkàsọ ilé rẹ̀, tí ó sì kú. Àyẹ̀wò ilé ìwòsàn fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ìpayà àjálù tó dé bá a ló mú ẹ̀mi rẹ̀ lọ.

Gẹ́gẹ́ bi ìròyìn ṣe sọ, Moyo kan dédé fi iṣẹ́ sílẹ̀ tó si ni òun fẹ́ lọ máa gbe ilú òyìnbó, nígbà tí ọkọ rẹ̀, Tunde Thomas ṣe àbẹ̀wò sí i ni ìlú oyìnbó, ni ìyàwó rẹ̀ sọ fún pé òun kọ́ ló ni àwọn ọmọ mejeeji ti wọn bi.

Níbáyìí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ ọgbẹ́ni Tunde Thomas tó d'ólóògbé, ti fí ìwé ẹ̀sùn sọwọ́ sí FCMB lati fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, Adamu Nuru ló fa ikú Tunde.

Wọn ni nítorí aṣemáse tó bá ìyàwó Tunde ṣe, to si han si pé ọmọ méjì ti òun ti n tọ́jú láti ọjọ́ pípẹ́, kìí ṣe àwọn ọmọ tòun.

Wọ́n ké pé àwọn àdarí àti olùdásílẹ̀ ilé ìfówópamọ́ FCMB àti ilé ìfòwópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà CBN pé, àfi dandan kí wọ́n dá ṣẹríà fún ọgbẹ́ni Adamu.

Ènìyàn ẹgbẹ̀run kan lé nígba ló ti buwọ́lu ìwé ẹ̀sùn náà gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà níbí, ti wọn si n beere pe kí banki naa yọ ọga agba rẹ níṣẹ́.

Nínú àtẹ́jáde tílé ifówópamọ́ náà fisita, gẹgẹ bi iwe ìròyìn Sahara ti wi, èyí ti Diran Ojo fọ́wọ́ sí ló ti sàlàyé pé, àwọn gbọ́ nípa ìròyìn tó ń tàn ká lóri ọ̀kan lára olùdarí ilé iṣẹ́ náà.

Ó ní àwọn ìgbìmọ̀ ilé ìfówópamọ́ náà tí bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn náà lóní wàrà n sesà.

"A ti gbọ́ nípa ìròyìn tó n tàn kálẹ̀, lórí ayélujára àti nínú àwọn ìwé ìròyìn kan, lórí ọ̀kan lára àwọn ọgá àgbà FCMB Muru Adam, ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ wá tẹ́lẹ̀rí, Moyo Thomas àti ọkọ rẹ̀ Tunde Thomas to ti d'ólóògbé"

"Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀rọ̀ asiri lọkọ-laya ni, síbẹ̀, ikú ọgbẹ́ni Tunde àti ìwà àìtọ́ tó wáye tó èyi tí ìgbìmọ̀ ilé iṣẹ́ náà yóò mójútó, ayẹwo nipa rẹ yóò wáye ni kíakía."

"À rọ gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn láti bá wa faradaá, títí tí à ó fi parí ìwádìí wa àti pé, ó ṣe pàtàkì láti bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹbí méjèèjì".

À ń ṣe àgbéyẹ̀wò, à ó si jábọ̀ fún yín tí a bá a parí "