You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Police Brutality: Ọlọ́pàá kan sọ pé òun ní láti ṣàyẹ̀wò ìlédìí ǹkan oṣù Arabìnrin kan kó tó lè kọjá
Iwadii ti fihan pe awọn ọlọpaa ni orile-ede Australia, paapaa ni ilu Sydney, maa n ni ki awọn obinrin bọ aṣo wọn ti wọn ba n ṣe ofintoto wọn.
Koda, wọn ni awọn agbofinro wọnyii maa n ni ki awọn obinrin tu aṣọ wọn silẹ lati woo boya wọn gbe oogun oloro tabi bẹẹkọ.
Eyi ko ṣẹyin bi ọlọpaa kan ṣe ni ki arabinrin kan yọ nkan iledi to dabi idigo ti awọn oloyinbo n pe ni Tampoon to fi n ṣe nkan oṣu rẹ nitori o fẹ yẹ ara rẹ wo lọna ati ṣe ofintoto.
- Wo àwọn òṣìṣẹ́ kólẹ̀-kódọ̀tí tó ń fi ẹ̀mí wọn wéwu kí Abuja leè mọ́ tónítóní
- Mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ń bá àwọn tí a jọ díje nínú ìdìbó abẹ́lé sọ̀rọ̀ kí àláàfíà léè jọba - Akeredolu
- Wo àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa 'Awawa Boys', ọ̀kan lára ẹgbẹ́ òkùnkùn tó n dá Eko rú
- Adarí àjọ NDDC, Pondei ṣetán láti sọ ohun tó mọ̀ nípa ìwàdíì tó bá ti gbádùn- NDDC
Ọpọlọpọ iṣẹlẹ yii waye ni awọn gbegede ariya orin kikọ ọlọdọọdun.
Awọn obinrin ti wọn ti hu iru iwa yii si ṣalaye pe igbesẹ ayẹwo gbogbo ara eeyan yii maa n jẹ ki o dabi ẹni pe wọn kii ṣe eniyan, abi eniyan ti wọn ko bikita fun ni awujọ.
Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa New South Wales ti ni awọn yoo ṣe iwadii ẹsun naa yẹwo finifini ati pe awọn yoo si gbe abajade iwadii naa sita.
Ajọ Law Enforcement Conduct Commission to fi iwadii naa lede rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati tọrọ aforijin ni ọwọ obinrin ti wọn ni ko yọọ nkan oṣu rẹ naa.
Wọn si fikun un wi pe ọlọpaa miran to ṣe nkan to buru ju bẹẹ lọ, ki wọn kọ iwe lọ rọkun nile fun un.
Iwadii naa bẹrẹ lẹyin ti awọn obi awọn obinrin ti nkan wọnyii ṣẹlẹ si lọ fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa abi ti wọn ba ri awọn iṣẹlẹ bẹẹ lori ẹrọ ayelujara.
Bakan naa ni ajọ to ṣewadii naa fikun un pe awọn eniyan n bere fun etọ ti awọn ọlọpaa yii ni labẹ ofin lati ṣe iru ofintoto bẹẹ, ati wi pe ki atunse ba eto ofintoto awọn ọlọpaa lorilẹ-ede naa.