Surrogate: Ibi táwọn kan ti fẹ́ yọ oyún, ni Judith ti bẹ̀ wọ́n fún pàsípàrọ̀

Àkọlé fídíò, 'Ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ t'óyún máà bàjẹ́ lára mi ni mo tó rí àànú gbà'

Ẹ̀ẹ̀mẹ́jọ ní oyún walẹ̀ lárá Akinwumi Judith kó tó di ìyá ìbejì, àmọ́ ohun toju rẹ ri ko to dohun, o kọja ohun to yẹ kẹni ọjọ ori rẹ ri.

Ibi to koju si ẹnikan, ẹyin ma lo kọ si ẹlomiran.

Nibi táwọn kan ti fẹ́ yọ oyún lọsibitu, ni Judith ti rina pade wọn nigba ti iṣoro rẹ yii kọkọ bẹrẹ to si n bẹ̀ wọ́n fún pàsípàrọ̀ - Bawo ni wọn ṣe fẹ ṣe e?

Kii kuku ṣe pe ko loyun lataarọ dalẹ ri, o n loyun, ọmọ a dagba de ibi kan ṣugbọn ile ọmọ funrarẹ ko dagba tẹle ọmọ ninu - Kayefi.

O gbiyanju ti ti ti kò gbọ́ wẹ̀ẹ́nn wẹ̀ẹ́n ọmọ ìkókó àfìgbà tí ẹlomiran ba a gbe oyun

Ṣe ẹ mọ̀ pe awọn dokita o kuku ni ijaya ọrọ to tobi lati sọ, tori ọrọ kii tobi titi loju tiwọn, wọn a f'ọbẹ bu u ni.

Dokita ba sọ fun un pe "a ti ṣa gbogbo ipa wa lọna ti a mọ ti a si ro pe a lee lo".

Ọpẹlọpẹ dokita mii ti o ba nibi to tun wo o pe kawọn tun ṣi lọ lati bẹrẹ ayẹwo lakọtun, lo ba ri bẹbẹ to ju bẹbẹ lọ.

"Esi ayẹwo sọ pe ile ọmọ mi kere ju, mi o le gbe oyun fun iye oṣu mẹsan ti wọn maa n fi gbe oyun".

Gẹgẹ bi abiyamọ, ironu wo lo maa kọkọ gba ọkan ẹyin naa?

Ẹ wo ohun ti Judith la kọja ninu fidio yii ati bi o ṣe ri padadi iya aburo.