EFCC: A ó ri dájú pé Diezani padà wálé láti jẹ́jọ́ ìwa jẹgúdújẹrá

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti ni awọn yoo ri daju pe Minisita fun epo rọbi, Diezani Allison-Madueke to n jẹjọ iwa jẹgudujẹra yoo pada wale, ki ọdun to pari lati wa jẹjọ rẹ.

Alaga Ajọ EFCC, Ibrahim Magu lo fi eyi lede lasiko to ṣe abẹwo si ẹka ileeṣẹ EFCC to wa ni ilu Ibadan.

Magu fi ẹsun kan awọn alabaṣiṣẹpọ wọn nilẹ okeere pe, wọn n daabo bo Diezani ni Ilẹ Gẹẹsi lati dena ati wa jẹjọ rẹ lorilẹede Naijiria.

Amọ o fikun pe, ajọ naa ti bẹrẹ si ni lo ọna miran lati fi ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni ilẹ okeere lati ri wi pe Minisita fun epo bẹntirolu tẹlẹri naa, pada wa sile lati wa jẹjọ ẹsun iwa ibajẹ.

Alaga ajọ EFCC ni, inu oun bajẹ gidigidi pẹlu bo ṣe nira, to si ṣoro lati jẹ ki awọn to n wu iwa ibajẹ fi oju winna ofin, ki awọn ẹlomiran le kọgbọn nipa rẹ.

Magu ni awọn ọmọ Naijiria n sa ipa wọn lati fi oju awọn ọbayejẹ han, o ni ki wọn tubọ tẹra mọ iṣesi naa, ki awujọ lee dara si.

Nipa eto idibo gbogboogbo to kọja, Ọga Ajọ EFCC naa fikun pe, awọn ri daju wi pe awọn gbogun ti iwa rira ibo ati tita ibo lorilẹede Naijiria.

Ìríwísí àwọn aráàlú bí EFCC ṣe kó afurasí ọmọ yahoo 49 ní Ibadan

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti fi panpẹ ọba mu awọn afurasi awọn ọmọ yahoo mọkandinlaadorun ni ilu Ibadan.

Ẹka Ile iṣẹ EFCC ni Ibadan lo mu awọn afurasi naa ni ile igbafẹ to gbagbajugbaja ni ilu ọhun, iyẹn Club 360 to wa ni opopona Akala ni Oluyole Extension ilu Ibadan, ipinlẹ Oyo.

Ọju opo Twitter EFCC ni iroyin naa ti n ja rain, ti ọpọlọpọ eniyan si n fi ero wọn han nipa iṣẹlẹ naa loju opo ikansiraẹni ọhun.

EFCC ni awọn mu awọn afurasi naa lẹyin ti wọn ṣe iwadii finifini ni ọ̀wọ alẹ lẹyin ti awọn gbọ pe awọn oniṣẹ magomago ati gbajuẹ n fi agbegbe naa ṣe ibugbe.

Bakan naa ni wọn ni awọn kọ orisirisi ọkọ, ẹrọ ilewọ ati awọn nkan miiran lasiko ti wọn n ṣe iwadii naa.

Ajọ EFCC fi kun unpe iwadii ṣi n lọ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ ọhun, ti awọn si ti bẹrẹ ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn afurasi naa.

Amọ lara awọn ọmọ Niajiria to fesi si ọrọ yii bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, ati wi pe EFCC ko lee sọ wi pe gbogbo awọn ti wọn fi panpẹ ọba mu naa ni afurasi 419.

Bakan naa ni awọn miran rọ ajọ EFCC lati ri i wi pe awọn ṣe iwadii finifini lori awọn ti wọn mu, ki wọn ma baa fi iya jẹ alaiṣẹ.