You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
EFCC: EFCC mú Ọmọ ọdún 17, afurasí mẹ́jọ tó ń ṣe yahoo-yahoo ní Íbàdàn
Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹ-ede Naijiria, EFCC ti tẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan ti wọn ni wọn gbamu fun ẹsun lilu jibiti lori ayelujara, iyẹn yahoo-yahoo.
Opin ọsẹ to kọja ni ẹka ajọ naa to wa ni ilu Ibadan mu ọdọmọkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Abdulrahaman Qozeem atawọn mẹjọ miran kaakiri ilu Ibadan.
- Ìkọlù agbébọn tó ṣékú pá ọmọ ogún Niger 89, iṣẹ́ bọ lọ́wọ́ Ọgágun àgbà
- Fọ́fọ́ ní ilé ẹjọ́ kún fún ìdájọ gomina ìpínlẹ̀ Kano, Imo, Sokoto, Benue, Plateau àti Bauchi
- Ǹjẹ́ o mọ ipa tí ẹja Panla kó lásìkò ogun abẹ́lé Biafra?
- Ọdún 21 tí mo fí sun inú mótò- Ọmọ Naijiria ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
- Ìjọba Canada kò gbó nípa ìgbéṣẹ̀ Harry àti Meghan láti wá sí ilẹ̀ wọn
Gẹgẹ bi ajọ EFCC ṣe ṣalaye, ọwọ tẹ awọn eeyan naa lẹyin ọpọ iwadii lori iwa ọdaran yahoo-yahoo ti wọn yan laayo.
Gẹgẹ bi wọn tun ṣe fi kun un, awọn ohun ini olowo iyebiye bii ọkọ ayọkẹlẹ mẹfa pẹlu oniruuru ẹrọ ibanisọrọ, kọmputa alagbeka, iwe irinna silẹ okeere atawọn iwe miran to jẹ ayederu iroyin ni wọn ba lọwọ awọn afurasi naa nigba ti ilẹ mọ ba oloro wọn nita gbangba.