You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Child Abuse: Ọmọ ọdún mẹ́wàá ń ké ìrora lẹ́yìn tí ọ̀gá tì í sínú àrò búrẹ́dì
Irora nla ni ọmọkunrin ọdun mẹwa kan to jẹ ọmọ ileewe almajiri, Nafiu Usman to ti n jẹ irora lati igba ti wọn ti fi ẹsẹ rẹ mejeji jona nileeṣẹ burẹdi kan lori ẹsun pe o ji burẹdi oni ọgọrin naira (N80).
Lai lai, ko si ẹni to lee ni imọlara iru irora ti o la kọja bi ọga rẹ ṣe n ti ẹsẹ rẹ bọ inu iho ina to n jo hii hii.
Ọpọ awọn ara ipinlẹ Gombe ni ọrọ yii ṣi n ya lẹnu idi ti oludari ileeṣẹ burẹdi naa, Idris Abubakar yoo kan ṣe dede jo ẹsẹ ọmọ ọdun mẹwa nina ninu ina aro ti wọn fi n ṣe burẹdi.
Ẹgbẹ kan to n ja fun ẹtọ araalu Muryar Talaka sọ fun BBC pe ọwọ ti tẹ afurasi naa ṣugbọn ti wọn tun pada da a silẹ nigba ti oku ọmọ naa si wa nile rẹ.
Ahmed Sulaiman to jẹ adari ẹgbẹ Muryar Talaka sọ fun BBC pe oun bẹ ọmọkunrin naa wo ti olukọ ile keu si ti n tọju ara rẹ.
- Ọmọ ọdún márùn-ún, àgbà mẹ́rin ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀pá bẹntiróò tó gbiná ní Abule Egba lọ - LASEMA
- Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP fẹ̀hónúhàn l'Abuja lórí ìdájọ́ ílé ẹjọ́ gíga jùlọ
- Mo kàn fẹ́ fi ọmọ tó sọnù gba owó lọ́wọ́ Sọtitobire ni - Afurasí
- Àwọn ará South-Africa yarí 'torí gbọ̀ngàn kọ̀ ìgbéyàwó abo-sábo
- Ẹ̀yin ẹ máà wò ó, ó ṣeéṣe kí APC túká lẹ́yìn ìṣèjọ́ba Buhari!
Ni agbegbe Bajoga ni ijọba ibilẹ Funakaye, ipinlẹ Gombe ni Usman wa lati wa kọ ẹkọ keu lati odidi Tafawa Balewa, ipinlẹ Bauchi.
Ahmed ni "oun to ṣẹlẹ ni pe ọludari ile iṣẹ burẹdi naa fi ẹsun kan ọmọkunrin ọhun pe o ji burẹdi lo ba ti i sinu iho ina ti wọn fi n yan burẹdi.
Iroyin ti a gbọ ni wi pe ọga ileeṣẹ burẹdi yii ko ẹsẹ Nafiu sinu ina aro ti wọn da si abẹ burẹdi, nigba to yọ ọ jade to ri i pe ko jo o daadaa o tun ju u sinu ina lẹẹkan sii.
Ko pẹ rẹ ni ọlọpaa tu ọga ileeṣẹ burẹdi naa silẹ ṣugbọn ọmọ ti wọn jo ẹsẹ rẹ nina ṣi wa ninu irora kikan.
Nigba to kuro ni atimọle ọlọpaa, o lọ bẹ ọmọ naa wo nile ṣugbọn ọga ile keu kan ti tọju ara ọmọ naa.
Ṣugbọn adari ẹgbẹ Muryar Talaka, sọ pe afurasi ọhun kuro ni atimọle lẹyin ti eekan kan ninu ilu lọ gba beeli rẹ.
Bakan naa o ni lọgan ni wọn ti ṣe iwe ẹri sita pe arun ọpọlọ n da Idris ọga ileeṣẹ burẹdi ọhun laamu.
ẹwẹ, nigba ti ileeṣẹ BBC kan si alukoro ọlọpaaa agbegbe naa o fesi pe oun ko tii gbọ nipa iṣẹlẹ yii ṣugbọn oun yoo kan si BBC pada lori bo ṣe jẹ bi wọn ba ti gbọ iroyin kankan.