Operation Amotekun: Atiku ní ẹ̀ṣọ́ alábòò Amọtẹkun yóò ṣ'èrànwọ́ lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ninu ibo gbogboogbo ọdun 2019, Atiku Abubakar naa ti kede atilẹyin rẹ fun ẹṣọ alaabo Amọtẹkun.

Ninu ọrọ rẹ, Atiku ni idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ tabi ọlọpaa ẹkunjẹkun yoo ṣe iranwọ lori eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria.

Atiku fọrọ yii lede lọjọ Aiku lẹyin ti minisita fun ọkọ ofurufu tẹlẹ ri, Femi Fani-Kayode sọ pe ata akara ti ko ran ikọ lọrọ ti ijọba apapọ sọ pe idasilẹ Amọtẹkun ko ba ofin mu.

Ninu atẹjade ti Atiku fi sita lati ọwọ oludamọran rẹ lori ọrọ iroyin, Paul Ibe, igbakeji aarẹ orilẹ-ede Naijiria tẹlẹ ni bi eto aabo ṣe ri ni nnkan bi ọdun mẹwaa sẹyin fihan pe ọrọ eto aabo nilo atunṣe ni Naijiria.

Atiku ni ko fẹẹ ma si ipinlẹ kan lorilẹ-ede Naijiria ti ko ni idojukọ tabi ipenija kan tabi omiran lori ọrọ aabo.

Atiku ni: ''Niwọn igba ti ipenija ipinlẹ kọọkan lori eto aabo ti yatọ si ra wọn, o tumọ si pe eto aabo ti ijọba apapọ nikan pese ko le dẹkun iwa ọdaran ati rogbodiyan ni Naijiria,

O ni idi eyi ni idasilẹ ẹṣọ eleto aabo bii Amọtẹkun fi ṣe pataki ni Naijiria.

Ẹwẹ, alaga ẹgbẹ awọn gomina ilẹ Yoruba to tun jẹ gomina ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Rotimi Akeredolu ti sọ pe awọn ko ṣe agbakalẹ Amọtẹkun lati tako iran mii ni Naijiria.

Akeredolu kilọ fawọn to n fi oju ẹlẹyamẹya wo Amọtẹkun pe eto aabo to munadoko lo jẹ awọn logun, eyi lo fa sababi ifilọlẹ Amọtẹkun.

Awọn ọtọkulu bi Ọjọgbọn Wole Soyinka, eekan ẹgbẹ Afenifere, Oloye Ayo Debanjo; agbẹjọro agba ati ajafẹtọ, Femi Falana, Oloye Olu Falae, ati Aarẹ Ọnakakanfo, Iba Gani Adams atawọn mii ni wọn ti sọrọ lati gbaruku ti eto Amọtẹkun.