You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
UK-Africa summit: Àǹfààní wo ló wà nínú Brexit fún Nàìjíríà àtàwọn orílẹ́èdè Afíríkà rèé
Lẹyin ti eto Brexit ba yanju tan ti UK si kuro lara ajọ EU, ijọba UK n gbero lati jẹ ki ajọsẹpọ rẹ lori idokowo pẹlu Afirika ko gberu sii.
BBC ṣe agbeyẹwo anfaani to le jẹ yọ fun ilẹ adulawọ nigba ti eto Brexit ba kẹsẹ jari nilẹ Gẹeṣi.
Akọroyin BBC, Matthew Davies BBC ṣalaye pe ọrọ le maa ri bi eeyan ti ro nigba miiran.
- Wòó nínú àwòrán: ìgbé ayé Harry àti Meghan ṣáájú ìyapa kúrò nílé Ọba
- Ìgbéyàwó ọkùnrin s'ọ́kùnrin, obìnrin s'óbìnrin ti di òfin ní Northern Ireland
- Ìjọba Canada kò gbó nípa ìgbéṣẹ̀ Harry àti Meghan láti wá sí ilẹ̀ wọn
- Wo ọ̀nà tí o fi lè bọ́ lọ́wọ́ àrùn jẹ̀dọ̀-jẹ̀dọ̀ 'Hepatitis'
- Amotekun: Kí ni iṣẹ́ tí Amotekun yóò máa ṣe gangan?
- Wo ipa tí Mayegun yóò ma kó ní ilẹ̀ Yoruba!
Ti gbogbo eto ba lọ ni irọwọ rọsẹ, ipari oṣu kinni ọdun 2020 yii ni UK fẹ fi ajọ EU silẹ patapata.
Lẹyin naa ni ilẹ Gẹẹsi yoo ṣe agbalẹ ọna ti wọn yoo fi maa ṣe idokowo pẹlu awọn orilẹede mii ti fi mọ ilẹ Afirika naa.
Ṣugbọn ọna wo gan an ni Afirika yoo fi jẹ anfaani ti ilẹ Gẹẹsi ba fi ajọ EU silẹ tan?
Akọwe ijọba UK lori ọrọ idagbasoke pẹlu ilẹ okere, Alok Sharma sọ pe ijọba ilẹ Gẹẹsi yoo ṣe imugbooro iṣowo ati idokowo pẹlu ilẹ adulawọ kete ti eto Brexit ba ti bẹrẹ.
O ni lori ọrọ yii gan an ni apero lori idokowo to n lọ lọwọ niluu London laarin ilẹ Gẹẹsi atawọn orilẹede Afirika da le lori.
Ti UK ba ti fi ajọ EU silẹ, anfaani awọn orilẹede Afirika yoo pọ si ọrọ idokowo.
Ilẹ Gẹẹsi yoo gbiyanju lati rii pe idokowo rẹ pẹlu ọrilẹede Amẹrika, South Korea ati Australia gberu si lẹyin to ba ti fi EU silẹ.
Ilẹ Adulawọ ni yoo kan ti yoo jẹ iru anfaani bayii lẹyin awọn orilẹede mẹrin yii.
Ni gbogbo igba ni Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson atawọn alatilẹyin rẹ maa n sọ pe Brexit yoo fun ilẹ Gẹẹsi lanfaani lati le duna-dura bo ti wu wọn lori ọrọ idokowo.