Buhari: Inú ìbànújẹ́ ni mo wà lórí ikú alága CAN tí àwọn Boko Haram pa

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Alaga ajọ ọmọlẹyin Kristi, ni ariwa Naijiria, Lawan Andimi ni iroyin kede pe awọn alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram ti pa.

Ṣaaju ni wọn kọkọ fi fọnran fidio kan sita nibi ti pasitọ Lawan ti n bẹ awọn ọmọ Naijiria ati ijọba pe ki wọn ran oun lọwọ ki wọn gba oun silẹ lakata awọn alakatakiti ẹsin Islam ti wọn mu oun mọlẹ yii.

Lẹyin ti fọnran yii jade ni awọn ajọ omọlẹyin Kristi lapapọ ke gbajare sijọba Buhari pe ko gbe igbesẹ to yẹ lasiko.

Lẹyin eyi ni iroyin jade pe wọn ti pa Pasitọ Lawan Andimi ti wọn jigbe ni ọjọ keji, oṣu kinni, ọdun 2020.

Lasiko ti awọn ẹni buruku yii kọlu abule Michika ni ipinlẹ Adamawa ni ila oorun ariwa Naijiria ni wọn gbe ojiṣẹ Olorun yii.

Bakan naa ni iroyin ni wọn ti n gbe igbese lati duna dura iye owo tabi ohun ti awọn alakatakiti ẹsin Islam yii fẹ gba lati fi ojiṣẹ Olorun naa silẹ ki wọn to paa.

Nigba ti BBC kan si Bisọọbu agba Stephen Dami-Mamza to jẹ adari alaga ajọ ọmọlẹyin Kristi CAN ni ẹkun ipinlẹ Adamawa lo ṣalaye ohun to mọ nipa iṣẹlẹ naa.

Biṣọọbu Stephen fidiẹ mulẹ pe oun ti ri fọto oku pasitọ Lawan ṣugbọn oun ko tii ri fọnran fidio ti wọn fi paa to n tan kalẹ kaakiri.

Aarẹ Muhammadu Buhari to n tukọ Naijiria lo ti fi soju opo twitter rẹ lori ayelujara pe ọrọ awọn alakatakiti ẹsin Islam yii n mu ibanujẹ ba oun lẹyin ti wọn n ṣebii pe wọn fẹ fi ojiṣẹ Olorun naa silẹ.

Buhari ni ipaniyan ojiṣẹ Olorun Lawan lati ipinlẹ Adamawa yii ko dara ati pe oun kẹdun pẹlu ẹbi pasitọ naa

Kini awọn ọmọ Naijiria n sọ?

Ero awọn ọmọ Naijiria ṣọtọọtọ lori ibanikẹdun Aarẹ Buhari pe ko tii mu ileri rẹ ṣe lori 2015 ati Boko Haram

Loju Ayemo, Aarẹ Buhari ko beere fun iranlọwọ lagbaye lati koju Boko Haram

Lọdọ Paulette ni tiẹ, ibanikẹdun kọ ni ọna abayọ nitori pe awọn omọlẹyin Kristi ni kini yii n fi si lọdọ ju ko to di pe suuru awọn onigbagbọ a tan ti a di ogun

Awọn bii Ondo Boy ke si aarẹ Buhari ati igbakeji rẹ, Oṣinbajo lati gbe igbeṣe to yẹ ki ọrọ to yi wọ.

Bẹẹ, awọn miran ki Buhari pe o ku iṣẹ, o si n gbiyanju pe:

Bakan naa ni adari ajọ MURIC bẹ awọn Kristiẹni ki wọn ma binu

Ojọgbọn Ishaq Akintọla to jẹ olori ẹgbẹ awọn musulumi MURIC ṣapejuwe ipaniyan naa pe ko dara rara.

O ni kini ẹṣẹ Pasitọ Lawan kọja pe o jẹ kristiẹni, ni eyi ti kii ṣe ẹṣẹ ni Naijiria nitori ẹsin to ba wu onikaluku lo le sin.

O ni ki awọn ọmọ Naijiria ma fi aaye gba ija ẹsin ati pe awọn musulumi kẹdun pẹlu ẹbi pasitọ naa ti awọn alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram pa.