IAAF vs AFN: Ó ṣeé ṣe kí Nàìjíríà má lè kópa nínú eré ìdárayá àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Esi o dá lori aṣẹ ti ajọ to n ri si ere idaraya lagbaye (IAAF) pa fun ẹka rẹ to wa lorilẹede Naijiria(AFN) gbedeke ọsẹ meji pere ni awọn fun wọn lati san owo ti IAAF ṣeesi san si apo asuwọn owo AFN.
Olukayode Abimbola Thomas to ti jẹ ọmọ igbimọ AFN tẹlẹ ri ṣalaye fun BBC pe ki saa igbimọ awọn to pari, bi ọrọ a sanwo, a ṣi owo fi ranṣẹ ti a sọ loke yii, bẹẹ gẹlẹ lo ri.
Ninu iwe ti wọn fi ranṣẹ si aarẹ AFN, Ibrahim Gusau ti oludari agba IAAF, Jee Isram fọwọ si, o ni lọfan ni wọn ti kan si AFN nigba ti aṣiṣe naa waye lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2018 pe ki wọn da ẹgbẹrun lọna aadoje dollar ($130,000) pada ninu ẹgbẹrun lọna ọgọjọ ($150,000) ti wọn ṣeesi fi ranṣẹ si wọn pada.
Kete ti o si ṣẹlẹ ni ẹni to jẹ akọwe nigba naa Amaechi Akawo lọ sọdọ ẹni to jẹ adari, Hajia Hauwakulu Akinyemi pe bayii bayii lo ri o ti Hajia naa si lọ sọdọ minisita fun ere idaraya.
Mnisita ba sọ fun wọn pe ki wọn lo owo naa fun awọn nkan ti wọn ko tii ri yanju niwọn igba ti kii ṣe owo wọn ṣugbọn wọn o s iru nkan ti wọn fi owo naa ṣe.
Ẹ̀wẹ̀, lẹyin oṣu meji, ajọ IAAF kọwe si Naijiria pe "a ṣi owo san fun yin o, ẹ da a pada". Nigba naa lọhun a ti ni ọga mii, Ibrahim Gusau to lọ ba minisita. Minisita si ṣeleri lati san owo naa pada.
Lọdun to kọja nibi ife ẹyẹ ilẹ Afirika, ikọ aṣoju tun wa ri minisita lati ajọ IAAF, ati aarẹ ana AFN ati aarẹ́ tuntun. Minisita si ṣeleri lati san an.
Lẹyin eyi wọn tun ti kan si AFN lọpọlọpọ igba ti minisita yoo tun ṣe ilere. Igba ti wn tun pade nibi ere idaraya lorilẹede Cote Divoir, wọn tun ran wọ́n leti ti minisita ko si ri owo san.
Ni ajọ IAAF ba yari pe ohun kohun bii owo to ba tọ si AFN lati ọdọ IAAF, wọn ko ni le gba a mọ. Nitori naa, lọdun yii wọn ko ni le ba wọn kopa ninu ere ije ti ilu Warri to ṣe pe aj IAAF lo ṣagbekalẹ rẹ tori aj naa ko fun wọn lowo ti wọn yoo lo.
Ni bayii, minisita yoo kuro lori alefa ni nkan bi ọsẹ meji. Nibi idije ere ije agbaye to waye ni Japan loṣu to kọja, wọn ti sọ fun Naijiria pe wọn ti bẹgi dina wọn, wọn o ni ri owo kankan gba mọ, wọn yoo si dena Naijiria lati ma le kopa ninu awọn ere ije IAAF mọ lagbaye.
"Ti Naijiria ba si kọ lati tẹle ofin tuntun yii, o ṣeeṣe ki wọn tun paṣẹ pe ki awọn asare ije wa to jẹ ọmọ Naijiria ma kopa mọ". O ni "bi a ṣe n sọrọ yi, minisita ko tii fọ ohunkohun".
Olukayode ni dipo bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọn n wọ Naijiria atawọn asare ije wa to lorukọ ninu ẹrẹẹ nitori $130,000.
Ẹwẹ nigba ti ile iṣẹ BBC kan si minisita atawọn mii tọrọ kan lati gbọ tẹnu wọn, pabo lo ja si.














