Election update 2019: Kí ló dé tí àwọn kan kò fẹ́ kí Atiku Abubakar pẹjọ́ nítorí èsì ìdìbò ààrẹ 2019?

Kii ṣe ohun ajeji ki oludije to ba fidirẹmi ninu idibo aarẹ lorilẹede Naijiria gba ile ẹjọ lọ lati beere fun 'ẹtọ' rẹ.

Yatọ si aarẹ ana, Goodluck Jonathan ti ko pẹjọ lẹyin to padanu idibo aarẹ lọdun 2015, ko fẹrẹ si awọn oludije gbogbo to ṣe ipo keji ninu idibo aarẹ lorilẹede Naijiria ti ko pẹjọ kotẹmilọrun esi idibo lati ọdun 1979.

Ni kete ti ajọ INEC kede esi idibo aarẹ naa ninu eyi ti Atiku ti ni ibo to le ni miliọnu mọkanla ti Buhari ti ẹgbẹ oṣelu APC si ni ibo to le ni miliọnu marundinlogun, ni oludije ẹgbẹ oṣelu PDP naa ti fi to gbogbo agbaye leti pe nitori awọn kudiẹ-kudiẹ ti o wọpọ lasiko idibo naa, gẹgẹ bii iwoye oun, ni oun yoo ṣe gba ile ẹjọ lọ lati pẹjọ kotẹmilọrun.

Amọṣa ohun to n ṣe ọpọ ni kayefi naa ni omilẹgbẹ ipe to ti n jade si Atiku Abubakar pe ko jeburẹ lori ipinnu rẹ yii.

Awọn wo lo ti lọ sile ẹjọ nitori ẹhonu idibo aarẹ lorilẹede Naijiria?

  • Idibo ọdun 1979: Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ lọ si ile ẹjọ lati pẹjọ kotẹmilọrun lori esi idbo to gbe Alhaji Shehu Shagari wọle. Igbẹjọ yii bẹrẹ ni ọjọ kẹwa oṣu kẹjọ ọdun 1979.
  • Idibo 2003: Muhammadu Buhari pẹjọ kotẹmilọrun labẹ Aṣia ẹgbẹ oṣelu ANPP.
  • Idibo 2007: Muhammadu Buhari pẹjọ kotẹmilọrun labẹ Aṣia ẹgbẹ oṣelu ANPP.
  • Idibo 2011: Muhammadu Buhari pẹjọ kotẹmilọrun labẹ Aṣia ẹgbẹ oṣelu CPC.

Nitori naa ko ṣe kayefi fun ọpọlọpọ nigba ti Abubakar Atiku, oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo aarẹ to waye ni oṣu keji ọdun 2019 kede pe oun yoo gba ile ẹjọ lọ lati pẹjọ kotẹmilọrun lori abajade idibo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ipe to ti wọle fun Atiku lori idibo naa.

Igbimọ alaafia lorilẹede Naijiria ninu eyi ti awọn olori orilẹede Naijiria tẹlẹ atawọn saraki-saraki lawujọ lo kọkọ kan si Abubakar Atiku fun ijiroro lẹyin eyi ti wọn wa rọ ọ lati sinmẹdọ lori ipinnu rẹ lati gba ile ẹjọ lọ.

Lẹyin eyi ni gbajugbaja amofin ati ajafẹtọ araalu kan, Olisa Agbakoba, SAN naa ke si Atiku pe ko ma ṣe lọ si ile ẹjọ lori ọrọ idibo naa.

Ni bayii, awọn oludije fun ipo aarẹ mẹrindinlogoji ni wọn tun ti bọ sita bayii pẹlu arọwa si Atiku Abubakar pe ko jogun o mi lori ọrọ a n pẹjọ lori esi idibo naa.

Nigba ti eeyan ba gbee yẹwo pe igba mẹta ọtọtọ ni aarẹ Buhari ti awọn eeyan ati ẹgbẹjẹgbẹ yii n tori parọwa yii ti gba ile ẹjọ lọ lẹyin to padanu idibo sipo aarẹ lorilẹede Naijiria, ọpọ lo ti n kọ lominu idi ti awọn eeyan ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ wọnyi ko ṣe fẹ ki Atiku gba ile ẹjọ lọ.

'APC fẹ fun Atiku lokun lọrun nitori ọr ile ẹjọ'

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, onwoye ọrọ to n lọ lawujọ, Ọmọlolu Akinwande ni ko si idi fun awọn eeyan lati maa rọ Atiku pe ko maa ls sile ẹjọ. Ọgbẹni Akinwande ni ara igbesẹ ti yoo mu idagbasoke ba eto iṣejọba awarawa lorilẹede Naijiria ni nitori ile ẹjọ naa ni ọna abayọ fun ẹnikẹni to ba ni ẹhonu kan tabi meji nipa eto idibo.

Bakan naa lo koro oju si ohun to pe ni igbesẹ ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣejọba lati fẹ fun Atiku lokun lọrun lati tẹ ẹ jẹjẹ lori ẹhonu rẹ fun esi idibo naa.

"Pẹlu bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n gbe igbesẹ to jọ bii ọna ati pa kẹkẹ mọ atioro Atiku lẹnu. Awọn alaṣẹ gbọdọ fun ẹgbẹ alatako lanfani ati maa wi tẹnu wọn."