Wọn yi lawọn ariran ti o kùnà lórí ẹni tí yóò di ààrẹ Naijiria.

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ko jẹ tuntun mọ pe awọn wolii orilẹ-ede Naijiria a máa riran nipa ohun gbogbo.

Bi wọn ko ba riran nipa ajalu ti yoo ṣẹlẹ, wọn a si ma fun ara ilu ni iro nipa awọn ti yoo padanu ẹmi wọn tabi ti yoo jẹ ipo kan tabi omiran ninu ijọba.

Saaju idibo ọdun 2019 awọn olori ẹsin Naijiria kan kede asọtẹlẹ nipa ẹni ti yoo jẹ oye Aarẹ Naijiria, awọn Sẹnẹtọ ti yoo jawe olubori ati awọn ipo miran ninu ijọba lawọn ipinlẹ kan ni Naijiria.

Idibo aarẹ ti waye a si ti mọ ẹni to gbegba oroke.

Bakan naa ni ti ibo awọn aṣofin. Njẹ awọn olori ẹlẹsin wọnyi jana nipa asọtẹlẹ wọn abi ofutufẹtẹ lasan ni iriran wọn jẹ?

A ṣe agbeyẹwo awọn kan ati asọtẹlẹ wọn nipa ẹni ti yoo jẹ oye nijọba ,njẹ wọn jana abi wọn kuna ni?

Faruq Onikijipa ati Bukola Saraki

Oniwaasu ẹlẹsin Islam yi ninu fọnran fidio kan ti o gbalẹ loju opo ayelujara ṣeleri pe ko si ẹni ti yoo yọ Aarẹ ile aṣofin agba Bukola Saraki kuro nipo rẹ.

Ọrọ yi mu ikunsinu wa fun awọn eeyan Ilorin paapa julọ awọn ti wọn kọrin o to gẹ fun Saraki.

Awọn eeyan ka ọrọ rẹ wewo wọn si lọ dibo, ababọ ibo ni pe Bukola Saraki fidirẹmi ninu ibo.

Wolii Austin Moses ati Omoyele Sowore

Omoyele Sowore ni wolii yi riran si wi pe yoo jẹ aarẹ Naijiria ti o si ni Olorun ni o fi iran naa han oun.

Ninu fọnran fidio rẹ́ towa loju opo You tube, o ni o nira fun oun lati jẹ́ iṣẹ yi pe Sowore ni Olọrun fẹ lo lati tun Naijiria ṣe ṣugbọn oun yoo jẹ.

Sowore kopa ninu idibo lootọ ṣugbọn ko jawe olubori ninu idibo, koda orukọ rẹ ko si lara awọn mẹta to lewaju ninu ibo aarẹ.

Wolii Akindodunse ati aarẹ ọdọ

Ikilọ ni wolii yi tilẹ fi sita fun Aarẹ Buhari pe ki o ma ṣe daba ati dije dupo aarẹ.

Gẹgẹ bi ohun ti o sọ, o ni Olorun sọfun oun pe saa kan ṣoṣo ni Buhari yoo ṣe ati wi pe ti o ba ṣesi polongo idibo yoo ku ni.

Buhari kopa ninu ipolongo idibo koda o tun dije dupo aarẹ. Ẹyin naa mọ ibi ti ọrọ pada ja si pẹlu abajade ibo.

Aarẹ ọmọ ọdun mẹ́rìndínlọ́gọ́rin ni Naijiria dibo yan, Muhammadu Buhari si ni orukọ rẹ.

Wolii David Aderemi Babalola

Atiku Abubakar ni oludije ti wolii yi sọ pe oun riran si ti o si fẹ le fi ogun rẹ gbari pe bẹẹ ni yoo ri.

Ninu fọnran fidio rẹ́ to wa lori ayelujara o sọ pe ''Lọdun maarun un sẹyin mo sọ bẹ nipa Atiku,lọdun mrin sẹyin Olorun sọ b fun mi nipa Atiku''

Abalọ ababọ asọtẹlẹ r ni pe Atiku fidirẹmi ninu idibo aarẹ ọdun 2019.

Guru Mahraji jana?

Ni tirẹ Olùdásílẹ̀ ìjọ One Love Family, Satguru Maharaj sọ pe ààrẹ Muhammadu Buhari tó ń dije lábẹ àsía ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Party (APC), ni yóò fidi alátako rẹ̀ Alhaji Atiku Abubakar, tó ń dije lábẹ́ égbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party(PDP) janlẹ̀ .

Ni èyí tí o dẹ padà ri bẹẹ.