Kamaru Usman: Ọmọ Áfíríkà àkọ́kọ́ tó gba ìgbànú ẹ̀yẹ ẹ̀ṣẹ́ kíkàn UFC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Kamaru Usman ti orukọ inagijẹ rẹ n jẹ Nigerian Nightmare ti di ọmọ ilẹ Afirika akọkọ ti yoo gba igbanu ẹyẹ fun ẹṣẹ kikan ti idije Ultimate Fighting Championship.

Usman din dundun iya fun Tyron Woodley lati di ọmọ Afirika akọkọ ti yoo bori ni idije naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eyi si tun mu ko di ọmọ orilẹ-ede Naijiria akọkọ ti yoo gba igbanu ẹyẹ Welterweight.

Idajọ awọn adajọ idije ẹṣẹ kikan naa to fi ni ami 50-44, 50-44 ati 50-45 lo fi bori.

Nibayii, ọkan-o-jọkan ọrọ si ni awọn eeyan ti n sọ lori ikanni ayelujara lori rẹ bayii.