Gbemisola Saraki: APC ló ni ìbò gomina ní Kwara ní Satide

Sẹnetọ Gbemisola Saraki ti ni oun yoo rii daju pe oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo gomina nipinlẹ Kwara ni yoo jawe olubori ninu idibo ọjọ kẹsan an, oṣu kẹta, ọdun 2019.

Gbemisola Saraki to jẹ ìbátan Aarẹ Ile Igbimọ Asofin, Sẹnetọ Bukola Saraki to jẹ ti ẹgbẹ oselu PDP fikun un pe AbdulRahman AbdulRasaq ni yoo fopin si saa gomina Abdulfatah Ahmed ti ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ naa.

Abilekọ naa to ti fi igba kan jẹ asojusofin lorilẹ-ede Naijiria sọ ninu atẹjade wi pe, ''Next Level'' ni ipinlẹ Kwara n lo.

Sẹnetọ Gbemisola Saraki ti fi igba kan jẹ́ aṣoju ẹkun Asa/Ilorin ni ọdun 1999 ko to lọ ṣe senetọ lọdun 2003 si 2011.

Ti a ko ba gbagbe, Bukola Saraki fidirẹmi ninu igbiyanju rẹ lati pada si ile igbimọ asofin agba lorilẹ-ede Naijiria ninu idibo gbogboogbo to waye ni Ọjọ Kẹtalelogun, Osu Keji, ọdun 2019.