ASUU Strike: Òtítọ́ wo ló wà nínú pé ASUU tún fẹ́ yanṣẹ́lódì?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti to jẹ ti ijọba l'orilẹede Naijiria ti sọ pe awọn ko gberero lati tun lọ fun iyanṣẹlodi oloṣu mẹta mi i.

Awọn olukọ naa, nipasẹ ọrọ kan ti ẹgbẹ ASUU fi sita lori ayelujara pe awọn n ro o lati tun lọ fun iyanṣẹlodi oṣu mẹta mi i, ti mu ki ọpọlọpọ eniyan fi ibinu han

Amọ ṣa, aarẹ ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Biọdun Ogunyẹmi ti kede pe irọ ni ọrọ naa ti awọn araalu ko gbọdọ ka si.

Oṣu Kọkanla ọdun 2018 ni ẹgbẹ ASUU lọ fun iyanṣẹlodi, o si lọ fun oṣu mẹta, ko to o di pe o wa sopin lọjọ keje, oṣu Keji ọdun 2019.