Nigeria 2019 Elections: Amòfin, àwọn òṣèré Tíàtà jà f'ẹ́tọ̀ọ́ àwọn olùdìbò àti òṣìṣẹ́ pàjáwìrì

Funke Akindele, Omotola Jalade Ekeinde, Kayode Ajulo

Oríṣun àwòrán, Kayode Ajulo, Funke Akindele, Omotola Jalade

Àkọlé àwòrán, Funke Akindele, Omotola Jalade Ekeinde, Kayode Ajulo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn kan lorilẹede Naijiria ti n polongo pe ki ijọba ṣe moriya fun awọn mọ Naijiria to padanu ohun kan tabi omiran nitori idibo ti ajọ INEC sun siwaju.

Lati igba ti ajọ eleto idibo Naijiria ti da ọjọ kẹtalelogun oṣu keji ọdun 2019 ni ọjọ tuntun ti wọn yoo di ibo yan aarẹ ati sẹnetọ ni awọn ọmọ Naijiria ti n fi ẹhonu han si igbesẹ naa.

Amofin Kayode Ajulo to jẹ onimọ nipa ofin ati ajafẹtọ araalu sọfun BBC Yoruba pe ko tọ ki ajọ INEC kàn ṣalaye idi ti wọn fi sun eto idibo naa siwaju.

O ni "owo ni awọn eeyan maa n na lati lọ dibo - bii awọn ti yoo rinrin ajo tẹbi tara wọn lọ si ilu mi i lati dibo, to fi mọ awọn to ti ile iṣẹ ati ile itaja wọn pa, eyi to tumọ si pe o yẹ ki ijọba tun sọ pe gba, ẹ ma binu".

Kayode lo apẹrẹ epo ọfẹ fun gbogbo araalu "nitori wi pe o ri i pe ko si ẹni ti ọrọ epo ko kan lorilẹede Naijiria, yala wọn jade nile tabi agbẹ ni wọn, bi owo epo ba lọ soke tabi wa silẹ, yoo kan alata, onidiri tabi oniṣẹ ọba."

Àkọlé fídíò, Akeredolu: Kìí ṣe Buhari ló wà nídìí rẹ̀, ẹ jẹ́ ká gbà pé àmúwá Ọlọ́hun ni"

Oun to n ja fun ni pe ki ijọba ṣaa ni ki awọn ara ilu gba nkankan gẹgẹ bii ma binu yatọ si ki wọn fi ẹnu sọ ọ.

Lorii pe o lee jẹ bi ipolongo fun ẹgbẹ to wa lori alefa, Kayode ni ko lee ri bẹẹ nitori wipe ati ẹgbẹ to wa lori alefa ati awọn ẹgbẹ oṣelu to ku ni yoo jẹ anfani rẹ.

O ni ki ijọba wo awokọṣe awọn orilede mii to ti ṣe iru rẹ fun awn araalu lati pọn wọn le.

Ẹwẹ, àwọn oṣere tiata naa ko simi ẹnu lori ohun ti awọn ọmọ Naijiria la kọja lakoko yii, paapaa awọn agunbanirọ atawọn mii to jẹ oṣiṣẹ sarenbaja fun ajọ INEC.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post