#BBCNigeriaElections: Ọmọ Ogun iṣẹ́ yá -Adarí àjọ elétò ìdìbò Ogun

Àkọlé fídíò, #BBCNigeriaElections: Ọmọ Ogun iṣẹ́ yá -Adarí àjọ elétò ìdìbò Ogun

O ni ko saaye fun agbopfinro kankan lati gbe ibọn nibudo idibo rara.

Ọjọgbọn Abdul Ganiyu Raji to jẹ alakoso eto idibo nipinlẹ Ogun ba BBC Yoruba sọrọ ni kikun lori awọn igbaradi ti ajọ naa ti ṣe ki eto idibo ọjọ Satide le kẹsẹ jari.

O ni agbofinro kankan ko ni gbé ìbọn, tabi mu ọ̀bẹ, àdá, ọ̀ks tabi ohun ìjà kankan lọwọ nibudo idibo ki ẹ̀rù ma le ba awọn oludibo.

Ojọgbọn naa gba awọn oludibo nimọran ki wọn jade sita wa dibo lai fooya, nitori eto aabo to peye wa fun ẹmi won lasiko idibo.

O ni o ṣeeṣe ki esi eto idibo bẹrẹ si ni jade lati irọlẹ ọjọ Abamẹta pẹlu ileri pé ti wọn ba ṣe n kaa tán naa lawọn a maa gbe esi na sita faraye.