BBC Nigeria 2019: Lekan Kingkong ní a kò fẹ́ ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ikú ọ̀dọ́ lásìkò ìbò

Àkọlé fídíò, BBC Nigeria 2019: Lekan Kingkong ní a kò fẹ́ ìtàsílẹ̀ àti ikú ọ̀dọ́ lásìkò ìbò

Adẹrinposonu lori ayelujara, Olalekan Ajao, ti gbogbo eeyan mọ si Lekan Kingkong ti n fi ewe ọmọ mọ awọn ọdọ leti lati la oju wọn lasiko ibo, ki wọn ma si se gba owo lọwọ awọn oloselu.

Bakan naa lo rọ wọn lati mase ta ọjọ ọla wọn nitori owo, eyi to lee mu ọla bọ mọ wọn lọwọ.

Lekan Kingkong parọwa yii lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori eto idibo to n bọ lọna yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lekan tun gba awọn oloselu nimọran, lati maa ranti pe awọn yoo fi ọmọ si aye lẹyin ti wọn ba papoda, idi si ree, to fi ni, o yẹ ki wọn gbe aye se rere.

O ni ko yẹ ki wọn gbagbe gbogbo ileri ti wọn se lasiko ipolongo ibo wọn, o si yẹ ki wọn mu gbogbo rẹ sẹ.

Lekan Kingkong wa rọ awọn oloselu, ọdọ ati araalu lapapọ, lati kẹyin si iwa jagidi-jagan, itajẹsilẹ ati iku ọdọ.