Toyosi Ogunseye: Èdè Yorùbá ò gbọdọ parún

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá ò gbọdọ parún - Toyosi Ogunseye

Àwọn alákoso ilé iṣẹ́ ìròyìn BBC Yorùba tí gbé ìròyìn àyọ dé ìpínlẹ̀ Ondo.

Èrèdí ìpolongo àti àbẹ̀wò sí ilé iṣẹ́ ìròyìn Suncity Fm ní agbègbè Bana ìpínlẹ̀ Ondo ní láti rii dájú pé àṣà, iṣẹ̀ṣe àtí èdè Yorùbá ò parun.

Alákoso àgbà tó ń sojú iwọ̀ọ-orun ile Afirika Toyosi Ogunṣeye ní ìdásilẹ̀ BBC news Yoruba kò ṣẹ̀yìn àti fẹ́ná sí èdè àti àṣà Yorùbá tó ń jó àjórẹ̀yìn lójoojúmọ́ pàápàá jùlọ láàrin àwọn ọ̀dọ́ òde òní.

BBC Yorùba sàbẹwo sí ilé iṣẹ́ Suncity

Toyosi àti Adedayọ
Àkọlé àwòrán, BBC Yorùba sàbẹwo sí ilé iṣẹ́ Suncity

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, BBC ṣe'filọlẹ Yoruba, Igbo ati Pidgin
Àkọlé fídíò, Yemi Alade Promo

Toyosi ní pàtàkì ìfọwọsowọ́pọ̀ tí BBC yoruba ń fẹ láàrin Suncity Radio ilé iṣẹ́ méjèèjì ní láti máá ṣe àgbélárugẹ fún àwọn ẹka ìroyin nínú ètò ọrọ̀ àjé, ètò ìlera, ètò òṣèlú, ìdárayá, àwọn ìwádìí ìjìnlẹ̀ àti onírúúru ìròyìn tí BBC maa ńgbejade

Lórí ètò kan náà tí ọ̀gá àgbà BBC Yorùba pẹ̀lú tí kopa, arábìnrin Adedayọ Owolabi rọ àwọn obi àti alágbàtọ lati kọ àwọn àṣà tó ń ṣe ìpalára fún èdè Yorùba sílẹ̀, pàápàá jùlọ nípa sisọ ọmọ ni orukọ tí kìí ṣe ti èdè Yorùbá àti sísọ èdè gẹ̀ẹ́sì sí ọmọ ní gbogbo ìgbà.

Àkọlé fídíò, Iko BBC Yoruba tuntun

Toyosi fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé BBC Yorùba ń lo ẹ̀rọ alagbéká gẹ́gẹ́ bí ibi ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ rẹ̀ nítorí pé ó jẹ ibi ti àwọn ọ̀dọ́ pọ̀ sí jùlọ láti maa mọ bo ṣe ń lọ lágbàyé facebook/bbcnewsyoruba, Instagram/ bbcnewsyoruba àti www.bbc.com/yoruba.