Naijiria lewaju ninu awọn orilẹede to n ko ibọn wọle

Ibọn ati ọta ibọn lori tabili

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Wahala abo to n mẹhẹ kun ara ohun to nfa kiko ohun ija oloro wọle

Laarin ọdun mẹrin sẹyin si asiko ti a wa yii, iye awọn ohun ija oloro to n wọle si orilẹede Naijiria ti gbe ẹnu soke pẹlu ida mejilelogun ninu ọgọrun.

Eyi jẹyọ ninu abajade iwadi kan eleyi ti ibudo kan ti a mọ si Stockholm International Peace Research Institute gbe kalẹ ni lọwọlọwọ yii.

Abajade naa tun salaye siwaju sii wi pe iye awọn ohun ija oloro ti o n wọ ilẹ Afirika ti wa silẹ pẹlu ida mejilelogun ninu ọgọrun.

Agbebọn kan gbe ibọn ati ọta ibọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ohun ija oloro ti o n wọ ilẹ Afirika ti wa silẹ

Laarin ọdun 2008 si 2012 ati ni ọdun 2013 si 2017 ni iye awọn nnkan ija oloro to n wọle sorilẹede Naijiria lọ soke.

Ọna mẹta ni ileesẹ ọmọogun lorilẹede Naijiria ti n foju wina ipenija abo-ikọ adukukulaja Boko Hara lẹkun ariwa, awọn ikọlu laarin awọn darandaran fulani ati agbẹ oloko naa o gbẹyin, bakanaa lawọn agbebọn lẹkun gusu pẹlu n dun mọhurumọhuru.

Akojọpọ awọn ibọn niwaju ologun kan

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Orilẹede Amẹrika lo n ko nkan ija oloro wọle julọ lagbaye

Pẹlu bi o se jẹ wi pe orilẹede Naijiria lo tobi ju ti a ba ni ki a sọrọ ni pa iye awọn eeyan sugbọn orilẹede Naijiria si n ko lara awọn nkan ija rẹ wọle lati ẹkun ariwa ilẹ Afirika.

Awọn orilẹede miran to wa lara awọn ti o nko nnkan ijagun oloro wọle julọ ni Afirika ni orilẹede Sudan, Angola, Cameroon ati Ethiopia.

Gẹgẹbii abajade iwadi naa ti se jẹ ko di mimọ, orilẹede Amẹrika lo ko nnkan ijagun oloro wọle julọ lagbaye, lẹyin naa ni orilẹede India, Saudi Arabia ati Egypt pẹlu.