Buhari: Mo tara lori ijinigbe ju ijọba ana lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede lọjọru pe ijọba oun tete gbe igbesẹ lọjọ kọkandinlogun osu keji ọdun yii ti ikọ Boko Haram ji aadọfa akẹkọ gbe lọ nileẹkọ girama to wa nilu Dapchi nipinlẹ Yobe.
O ni itara ijọba oun lori isẹlẹ yii gbopọn ju itara ijọba ana lọ lasiko tawọn Boko Haram ji awọn akẹkọ gbe lọ nilu Chibok, nipinlẹ Borno lọdun 2014.
Buhari fọwọ idaniloju yii sọya nibi ipade ilu kan to se pẹlu awọn ọba alaye atawọn olori agbegbe pẹlu awọn eeyan mii ti ọrọ Ilu Damaturu nipinlẹ Yobe gberu eyi to jẹ ara eto ti wọn la kalẹ fun abẹwo rẹ.
O fikun pe itara ijọba oun lati gba idande awọn akẹkọ Chibok lo mu ko seese fun wọn lati ri akẹkọ bii ọgọrun gba pada wale.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

"Bẹẹ ba gbagbe, eto ifikunlukun taa nse lo mu ki wọn tu awọn olukọ fasiti ilu Maiduguri silẹ pẹlu awọn osisẹ ọlọpa obinrin, awọn akẹkọ to fi mọ awọn agunbanirọ pẹlu."
O ni awọn ko si siyemeji peawọn akẹkọ Dapchi yoo ri idande gba lọwọ Boko Haram. Oun si lee fi ogun ọrọ yii gbari fawọn obi wọn,orilẹede Naijiria lapapọ ati awujọ agbaye pẹlu.
Buhari fi kun pe, awọn maa sa gbogbo agbara to ba wa nikawọ awọn lati ri daju pe finni ni adiẹ awọn akẹkọ yii ti oko eemọ bọ, ti wọn si fa wọn le awọn obi wọn lọwọ.








