Uefa Champions League gori afẹfẹ loni

Oríṣun àwòrán, AFP
Ajọ Uefa fẹ ki awọn oludari ifẹsẹwọnsẹ maa ṣe ibawi ti o yanranti fun awọn agbabọọlu ti o ba ṣe aṣemaṣe lori papa bi idije Uefa champions league yoo ṣe pada sori afẹfẹ lalẹ oni.
Ajọ naa sọ fun awọn oludari ifẹsẹwọnsẹ wipe ojuṣe wọn ni lati daabo bo awọn agbabọọlu nipasẹ pipese ijiya ti o tọ fun awọn aṣiṣe ninu awọn idije naa.
Eyi waye lẹhin ti Oludari agbabọọlu Manchester United, Pep Guardiola rọ awọn alaṣẹ liigi naa lati maa ṣe amojuto awọn agbabọọlu to n kopa ninu liigi naa lẹyin ti Leroy Sane fi ara pa lasiko ifẹsẹwọnsẹ kan to waye pẹlu Cardiff ninu idije FA Cup .
Awọn ifẹsẹwọnsẹ wonyi ni yoo waye ninu saa Champions League yii:
Ọjọ iṣẹgun, ọjọ kẹtala osu keji
FC Basel vs Manchester City
Juventus vs Tottenham Hotspur
Ọjọru, ọjọ kẹrinla osu keji
FC Porto vs Liverpool
Real Madrid vs Paris Saint Germain
Ọjọ iṣẹgun, ogunjọ osu keji
Chelsea vs Barcelona
Bayern Munich vs Besikta
Ọjọru, ọjọkọkanlelogun osu keji
Sevilla vs Manchester United
Shakhtar Donetsk vs Roma.












