You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Man allegedly rapes girl: Ọlọ́pàà fi ṣìkùn òfin mú okùnrin tó bá ọmọ ọdún 17 lòpọ́, tí ọmọ náà sì padà kú
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti ni awọn yoo gbe ọkunrin kan to fi ipa ba ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan lopọ, to tun pa ọmọdebinrin naa lọ sile ẹjọ.
Ninu atẹjade kan, agbẹnusọ ileeṣẹ naa ni ipinlẹ Nasarawa sọ pe awọn yoo pe Bako Anjeh lẹjọ ni kete ti wọn ba ti pari iwadii awọn lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Lọwọ yii, ọlọpaa ni ọrọ naa ti wa lakata ẹka ileesẹ naa to n ṣewadii iwa ọdaran, CID, ipinlẹ naa.
- Òkú obìnrin yìí kan ìlẹ̀kùn pósí gbà-gbà-gbà pé òun ò kú lọ́jọ́ ìsìnkú rẹ̀! Kàyéfì tuntun
- 'Ẹ yẹgi fún un'! Ọkùnrin ẹni ọdún 42 gba ìdájọ́ ikú lẹ́yìn tó pa Ọba aládé l'Ekiti
- Wo ǹkan 21 tó yẹ kí obìnrin mọ̀ nípa ojú abẹ́ rẹ̀, Vagina
- Kí ló fa gbas-gbos láàrín àwọn òṣèrébìnrin méjì, Laide Bakare àti Eniola Badmus?
- A kò mọ pásítọ̀ tó fẹ́ kó ọmọ ìjọ rẹ̀ lọ sí ọ̀run rí – CAN
- Ikú àwọn Sójà tọkọ-taya tí wọ́n gé lórí kò yẹ àwùjọ ọmọ ènìyàn rárá - Ààrẹ́ Buhari
- Ọmọ orílẹ̀èdè Lebanon tó gba 'One way' l'Eko fi ọkọ̀ fọ́ ẹsẹ̀ obìrin kan
- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ti sọ ìgbésẹ̀ tuntun tí wọ́n fẹ́ gbé nípa ẹ̀sùn àwọn tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ajá
- Ògo Naijiria yóò padà wá tí mo bá di Ààrẹ - Pasitọ Tunde Bakare
- Gueterres, Ìrìn asán ni ìrìn rẹ, tó o bá bẹ àwọn ibi tí Fulani ti n ṣe ọṣẹ́ ní Nàìjíríà- Akintoye
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye
Wọn ni lọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ni obinrin kan lọ si agọ ọlọpaa ni Akwanga lati fi ẹjọ afurasi naa sun lori bo ṣe gbiyanju lati fi ipa ba ọmọ oun lopọ inu yara rẹ.
Obinrin naa ni ọmọ oun kọ jalẹ.
Amọ, kaka ko fi ọmọ na silẹ, ni ṣe ni afurasi naa fun ọmọde naa ni oogun pakopako.
Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, lẹyin ti ọmọ naa mu majele naa tan ni ara rẹ rẹwẹsi, nigba naa ni afurasi ọhun ba ni ibalopọ.
Atẹjade naa ni "Ni kete ti a gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni a awọn ọlọpaa to wa lagbegbe Akwanga lọ sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ti a si fi ṣikun ofin mu afurasi ọhun."
Lẹyin naa ni wọn gbe digbadigba lọ sile iwosan ijọba to wa ni Akwanga fun itọju, ti wọn si gba ọrọ rẹ silẹ.
Lẹyinorẹyin, ọmọdebinrin na ku, wọn si ti gbe oku rẹ sile igbokupamọsi fun ayẹwo.