Pastor Taiwo Odukoya: Ọ̀fọ̀ míìràn tún ṣe Pasítọ̀ Taiwo Odukoya

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Pasitọ agba ijọ Fountain of Life Bible to wa ni ipinlẹ Eko bi ibeji rẹ Kehide Hassan ṣe tun di oloogbe.

Iroyin sọ pe arabinrin naa d'ologbe lẹyin ọsẹ diẹ ti iyawo ẹlẹkeeji pasitọ naa ku lẹyin to ti japoro lọwọ aisan jẹjẹrẹ fun ọdun meji.

Ọmọ Pasitọ Taiwo Odukoya, Tolu Ijogun lọ sisọ loju eegun ọrọ naa loju opo instagram rẹ lasiko to kọ sibẹ pe oun n selede lẹyin ibatan baba oun to ti duro gẹgẹ bi mama fun awọn ni gbogbo igba ti awọn nilo eniyan bi iya.

O kọ bayii pe, " Aunti mi "K" ọwọn, ẹni ti o sun mọmi julọ.... ẹyin ni ẹ maa n wa nibẹ fun mi ni ọpọ igba ti mo ba nilo iya mi julọ.

"Ẹ di mi lọwọ mu nigba ti e si ma n gba mi nimọran ... Lakotan ti mo ba sọ pe ayun yin ko ni mumi asọdun ni, Sun-un Re oo Aunti mi ọwọn "