You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bill Gates: Microsoft ṣetán láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún mílíọ̀nù márùn ún ọmọ Naijiria
Ileeṣẹ to n ri si imọ ẹrọ, Microsoft ati ijọba papọ ti buwọlu adehun kan lati da iṣẹ ti ko din ni ẹgbẹrun mẹtadinlogun silẹ fun awọn ọmọ Naijiria laarin ọdun mẹta si akoko yii.
Lara eto naa ni lati ṣagbekalẹ awọn irinṣẹ ti yoo mu ki ikanni ori ayelujara ja fafa sii ni Najiiria.
Igbakeji Aarẹ, Yemi Osinbajo lo fi ọrọ naa lede lasiko to ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ loju opo Twitter rẹ.
Microsoft sọ ninu atẹjade kan sọ pe awọn ti ni ifọrọwerọ pẹlu ijọba Naijiria lati jawe sobi bi eto imọ ẹrọ ni Naijiria.
Aarẹ ileeṣẹ naa, Brad Smith ni awọn yoo ṣe idanilẹkọọ fun nnkan bii miliọnu marun un eeyan lati asiko yii si ọdun marun un.
Lati le jẹ ki igbesẹ naa rọrun, Microsft ni awọn yoo ṣe idanilẹkọọ fun olukọ ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ti yoo ṣe idanilẹkọọ fun awọn ọmọ Naijiria atawọn oṣiṣẹ ijọba labẹ eto naa.
Microsoft fi kun un pe lara eto naa ni bi awọn yoo ṣe ran ijọba lọwọ lati gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria.
Bakan naa ni awọn yoo tun ṣiṣẹ papọ pẹlu ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC, lati mu adinku ba iwa jẹgudujẹra.
Igbakeji Aarẹ Naijiria, Yemi Osinbajo ni ibaṣepọ tuntun yii jẹ ọkan lara awọn ijiroro ti oun ti kọkọ ni pẹlu Aarẹ ileeṣẹ naa loṣu kinni ọdun yii, iyẹn Brad Smith.
Pupọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ikede naa.
- Ìdí tí a fi lé àwọn Fulani 42 tó ya bo agbègbè Okitipupa padà sí ìpínlẹ̀ wọn - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo
- Bola Tinubu: Ọlọrun kò ní gbà kí Naijiria tún la ogun abẹ́lé míràn kọjá
- Ọjọ́ mẹta péré lo ní báyìí láti ṣe àyẹ̀wò Covid19 ṣáájú ìrìnàjò wá sí Nàìjíríà!
- Bí àwọn gbajúmọ̀ ṣe pín rèé lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn jàndùkú agbébọn pa kọmíṣọ́nnà àti ọlọ́pàá, wọ́n dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá