You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Boko Haram: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní òun fẹ́ lo ẹṣin àti Ọ̀kadà láti ṣọ́ ìlú Abuja
Ileesẹ ọlọ́pàá nilu Abuja tí kéde pé òun yóò fi àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tó ń lo Okada àti ẹṣin ránṣẹ́ si àárín ìlú náà láti finmu finlẹ nípa àwọn ọ̀daràn.Atẹjade kan tí ọga ọlọpaa nilu Abuja, Mariam Yusuf fi síta lo sísọ loju ọrọ yii O fikún pé àwọn òṣìṣẹ́ náà yóò wọ àwọn agbègbè ìgbèríko lọ níbi táwọn ọ̀daràn fi le ṣe ibùba, tí mọto sì má le wọnú ìbẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Á ṣe ìwọ́de tako ọlọ́pàá láàrin ọjọ́ méje lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha - Yomi Fabiyi
- Ìdí táwọn agbófinró ṣe fẹ́ lo ẹṣin àti Ọ̀kadà láti dáàbò bo Abuja
- Tíṣà mu ọtí yó ló bá kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọmọdé lọ ilé ijó oníhòhò
- Gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ tẹ́ẹ ní ìpínu láti da ètò àbò àti àláfíà Nàìjíríà rú, ká ṣọ́ra o!
- Ìdí tí a fi lé àwọn Fulani 42 tó ya bo agbègbè Okitipupa padà sí ìpínlẹ̀ wọn - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo
- Senior Advocate of Nonsense, Eedris Abdulkareem fi àbùkù kan Keyamo nínú òrin tuntun
- Bola Tinubu: Ọlọrun kò ní gbà kí Naijiria tún la ogun abẹ́lé míràn kọjá
Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ni Abuja gbé igbesẹ náà lẹ́yìn tí ìròyìn ayélujára kan kéde pé ikọ Boko Haram ti kọlù agbègbè kan nilu náà.Àmọ́ ikọ ọmọ ogun alajumọse feto ààbò nilu náà tí ni irọ ni ìròyìn náà.
Yusuf ni ìdí rèé táwọn òṣìṣẹ́ agbófinró náà yóò fi wa ẹṣin àti ọkada láti máa tọpinpin ojú pópó àtàwọn ẹsẹkuku laarin ìlú náà.Ileesẹ ọlọpaa náà wá ń rọ àwọn aráàlú Abuja láti ṣe suuru nítorí kò ní sí ewu.
Gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ tẹ́ẹ ní ìpínu láti da ètò àbò àti àláfíà Nàìjíríà rú, ká ṣọ́ra o! - DSS
Ile ișẹ ọtẹlẹmuyẹ ni awọn ko ni fi oju Ire wo ẹgbẹ kankan labẹ ahesọ pe awọn n ja ijagbara eyi ti yoo maa da omi alafia ilu ru.
Ile ișẹ DSS fidi ọrọ yii mulẹ lọjọ Aiku ninu atejade kan ti wọn ti bẹnu atẹ lu awọn kọlọrọsi kan ti wọn n dunkoko mọ ijọba pe awọn n fẹ ipinya, eyi to si n da ifọwọsowọpọ Naijiria ru.
Eyi ti o jẹyọ laipẹ yii ni ti awọn adari ijoba Naijiria nigba kan sẹyin naa ti wọn n pe fun ayipada ijọba to wa lori alefa lọna ti ko tọ ti o si ni ki gbogbo ara ilu gbe igbesẹ.
"Eyi fi han pe eredi ti ẹni naa fi n se e ni lati da wahala silẹ ni Naijiria.
O ṣeni laanu pe ọpọ awọn to n pe fun nkan wọnyii jẹ ẹni a n buyi fun ni awujọ, ti o si yẹ ki wọn wa nidi otitọ ati igbelarugẹ orileede ati lati ma jẹ ki imọ taraẹni nìkan ba ilọsiwaju orileede yii jẹ", ọrọ DSS re.
Ile ișẹ naa fi kun un pe awọn ri gbogbo ọna ti wọn gba lati darapọ mọ awọn miran to wa ni ilẹ okere lati ko wahala ba Naijiria.
O ran wọn leti pe bi o tilẹ jẹ pe Ijoba awaarawa fi aaye gba ki awọn eniyan le sọ ero ọkan wọn, ko fi aaye gba ki awọn eniyan maa sọ isokusọ to le ko ba eto aabo orileede.
" Nitori idi eyi, awọn eniyan ati ẹgbẹ oni imọ taraẹni nikan ni a kilọ fun lati jina si awọn iwa yii ti o le da alaafia ati isopọ ilu ru".
Awọn gbajugbaja lawujọ ni lati sọra ṣe ki wọn si kora wọn ni ijanu lati ma sọ ọrọ ti yoo da wahala silẹ lawujọ, gẹgẹ bi atẹjade naa se sọ.
Laipe yii ni ile ișẹ ọtẹlẹmuyẹ pe awọn kan fun iforowanilẹnuwo sugbọn ti wọn sọ pe asigbọ ọrọ ni, nigba ti ẹlomiran sọ pe kii ṣe nkan ti awọn sọ ni awọn eniyan n tumọ.
Awọn ikilọ ile ișẹ ọtẹlẹmuyẹ yii jẹyọ latari bi orileede Naijiria se n koju eto aabo to mẹhẹ, ijingbe, ipaniyan, Idigunjale, ìgbésùmọ̀mí ati kikogun ja awọn eleto aabo jakejado Naijiria.
- Bí àwọn gbajúmọ̀ ṣe pín rèé lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn jàndùkú agbébọn pa kọmíṣọ́nnà àti ọlọ́pàá, wọ́n dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá
- Kò sí ẹ̀rí tó dájú tí a lè lò láti yọ Pantami kúró n'íjọba Buhari- Ilé aṣòfin l'Abuja
- Wo ìdí tí ìjọba Naijiria ṣe fòfin de gbogbo arìnrìnàjò láti India, Brazil àti Turkey
- Orí yọ ẹ́ o Baba Ijesha tí mi ò rí fídíò èpè tí wọ́n ní ò ń ṣẹ́, ǹkan tí mi ò bá ṣe fún ẹ... - Iyabo Ojo